AFCON 2019: Àwọn ọmọ Naijiria sọ̀rọ̀ lórí ìdíje Madagascar àná
Published
Ọpọ n ṣaroye pe awọn ko ri iṣẹ Mikel ati John Obi rara ni papa iṣere Alexandra.
Ni kete ti awọn agbabọọlu Naijiria pari idije wọn pelu MAdagascar ni BBC Yoruba jade fọrọ wa awọn ololufẹ Super Eagles lẹnu woYan àwọn tí o fẹ̀ fún ẹgbẹ agbábọ́ọ́lù ààyò rẹ.
Madagascar na Naijiria pẹlu ami ayo meji sodo Akọni ṣubú l'ójú ìjà, Madagascar fi 2-0 la Super Eagles mọ́lẹ̀ ni eyi to dun ọpọ ọmọ Naijiria.
Awọn eniyan Naijiria ti wọn na owo wa lati Cairo ati agbegbe rẹ wa ṣe koriya fún awọn Super Eagles ni Cairo ti fi aidunnu wọn han.
Wọn ni awọn agbabọọlu Naijiria ti dagba, wọn ko dẹ karamọ iṣẹ naa bo ṣe yẹ.
Koda wọn fi awọn agbabọọlu Naijiria wé ipa ti awọn ọmọ awọn keekeeke le ko lawujọ.