You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.

Take me to the main website

Ìjíròrò láàrin àwọn olùdíje ipò gómìnà Èkó

Àlàyé àti èrò nípa ìjíròrò láàrin àwọn tó ń du ipò gómìnà ìpínlẹ̀ Eko láti ìpàdé ìtagbangba BBC Yoruba.

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Abdulwasiu Hassan

  1. Ogunsanya lórí èéfín

    Ogunsanya ní mọto àti generator nìkan kọ́. Ilé ìdọ̀tí tí wọ́n kìí kọ́ lásìkò tí ó sì máa ń faa òórún tí kò ṣe ara loore. Wọn ò ṣètò ibi tí wón ó máa kọ idoti sì. Mọto tó ń yoruku ni wọn ò máa gba lọwọ wọn.

    Ogunsanya fi kúu pé ọ̀rọ̀ ìdọ̀tí ìpínlẹ̀ Eko abé ìjọba ìbílẹ̀ lọ yẹ kí o máa mójú tó idoti agbegbe, gbogbo ìṣe tó tọ́ sì ijoba ibile ti wọn ti gba lọwọ wọn ní wón a dá padà fún wọn wọn a máa recycle ẹ naa

  2. Adesanya lórí èéfín

    Adesanya ní èéfín to ń jáde lára àwọn mọto tó ti gbó lọ faa Àwọn ilé ìṣe náà di kún, òfin yóò wà láti ríi dájú pé ìwà ọ̀daràn ni wọn ò kaa kún tí wọn ò bá tẹle

  3. Ètò Gbadamosi lórí èéfín

    Gbadamosi ní Gebertor lọ ń Fà èéfín, bus náà kún un. Ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́jo ni yóò rí iná laarin oṣù 16.

  4. Lori Afẹ́fẹ́ tó dára

    Lori Afẹ́fẹ́ tó dára ( air pollution and environmental pollution ).

    Fafowora ní nǹkan tí wọ́n á ṣe ní láti máa lọ àwọn mọto ìgbàlódé tí kìí lọ Dissel mọ́ nù un. Wọn ò fi ààyè gba san diedie láti ra mọto ìgbàlódé gidi.

  5. Èéfín lókàn

    ìbérè lórí èéfín lókàn.

  6. Fafowora

    Fafowora sọ wí pé èèyàn mílọ́nù 22 lọ́ wà l'Eko tí ò sí Metro line, ìjàmbá lọ́ jẹ́ fún ará ìlú, wọ́n ṣetán láti ṣe metro line ni ìpínlè Eko, ènìyàn 22m lọ wà ní ìpínlè Eko New York Experience ni won máa lo tí wọn ba ti dé bẹ

  7. Ogunsanya lóríi súnkẹrẹ fàkẹrẹ

    Ogunsanya :Àwọn OKo ejò tó gbà ìlú Èkó kan di dandan kí a wo wọn kúrò, ona ojú ọmọ àti Raluwe náà ṣe pàtàkì

  8. Sún-kẹrẹ-fà-kẹrẹ

    Sún-kẹrẹ-fà-kẹrẹ ọkọ̀ ni ìbérè tó kàn.

  9. Ìdí tí Adesanya fi di olóṣèlú

    Adesanya sọ pé : Obìnrin tó ní ìgboyà ni ó jé, nítorí ìyá ń jẹ àwọn ènìyàn ìlú Èkó, wọn fẹ mú àwọn tó wà lábé afara kúrò nínú ìyá. Ilé ìwòsàn gaan ó ṣe fojú rí. Iya yìí ló faa tí wọn fi fe díje.

  10. Èrò ńgbà Olumuyiwa Fafowora

    Olumuyiwa Fafowora, dúpẹ́ lọ́wọ́ ilé ìṣe bbc fún anfani láti bá àwọn ará ìlú soro, ọmọ bibi ibeju Leki ni wọn. Ìlú Èkó ni wọn ti kà ìwé wọn, Lagos Poly, Gbobi college, won lo ilu oyinbo láti kàwé sii.

    Wọn darapo mo ìṣe àwọn ẹbí wọn..

    Fafowora ní "Nítorí pé ẹni tí ó bá jìyà rí kò lè mọ bí nkan ṣe rí, wọn jẹ olóṣèlú abele. Ìjọba gbodo mo ìyá tó ń jẹ àwọn ará ìlú kii se lati koko sì kooro"

  11. Nǹkan tí Omolara Adesanya fẹ́ ṣe

    Omolara Adesanya, wọn ṣíṣe fún 35 years ni CBN, ìdí tí wọn fi ń díje ni pé orisirisi nkan lọ dabi pé ó kú díè kaa tó, ètò eko, ilé ìwòsàn, ètò ààbò abbl lọ kú díè kaa tó.

    Nǹkan ti ilu yóò fi toro lọ gbé wọn wá sí ipò òṣèlú, èyí kò sì yẹ kí o máa lọ bẹẹ lai wá ojútùú sii kí àwọn tó wà leyin ìlú lè mọ pe iyato tí de

  12. Èròńgbà Gbadamosi

    Ogbeni Babatunde Olalere Gbadamosi. Gbogbo ìwé tó ká je ti orile-ede Naijiria kí ó tó lọ sise ni ilu oyinbo, wò lọ ọdún mẹtàdínlógún ni wọn wá dà ilé ìṣe silẹ.

    Ìṣòro tó pò ni ìpínlè Eko, ìṣe omi ona eto ìlera, ilé ìwé tí kò sì lọ faa tí wọn fi gbé ìgbà ìdìbò.

  13. Nǹkan mẹ́rin Ọmọbabìnrin Ogunsanya mójútọ́

    Ọmọbabinrin Ogunsanya pinu láti ṣe ohun merin gbòógì. Dídójú ti òfò kí ebi má pá ara ilu ni wọn ṣe gbé ìgbà idibo.

  14. Adebisi Ogunsanya

    Adebisi Ogunsanya ni olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú YPP. Adebisi jẹ́ ọmọ bíbí Ikorodu. Ó nímọ̀ nípa ìṣirò owó. Ó sì ní iléeṣé àdání.

  15. Babatunde Gbadamosi

    Babatunde Gbadamosi ni olùdíje fún egbé òṣèlú ADP. Ọmọ bíbí Ikorodu ni. Onísòwò ilékíkọ́ àti iléìgbé ni. Ó sì jẹ́ olùdíje gómìnà tẹ́lẹ̀rí lábẹ́ àsìá PDP.

  16. Omolara Adesanya

    Omolara Adesanya ni olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú PPC. Ọmọ bíbí Isale Eko ni. Onísòwo ni, abániṣètò ìnáwó ni pẹ̀lú. Ó ti ṣe olùdarí bánkì àpapọ̀ Nàìjíríà nígbàkan rí.

  17. Muyiwa Fafowora

    Omolara Adesanya ni olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú ADC.Ọmọ bíbí Isalẹ Eko ni. Onímọ̀ nípa iṣẹ ad'ójútòfò ni. Ó jẹ́ olóyè ẹgbẹ́ PDP nígbàkan rí.

  18. Ìpínlẹ̀ Èkó

    Ìpínlẹ̀ Eko jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìpínlẹ̀ tí kò ṣé e mú ṣeré ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà.

    Sún-kẹrẹ-fà-kẹrẹ ọkọ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìṣòro tí àwọn ará Eko ní.

    Ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ Eko ju ti orílẹ̀èdè Kenya lọ

  19. Àwọn èèyàn ti wà níkàlẹ̀

    Àwọn ènìyàn ti wa ni ikale báyìí tí wọn ń retí àwọn olùdíje fún àwọn nkan rí wọn ní fún wọn.

    Gbogbo àwọn olùdíje lọ ti wá ní kalẹ ADC, PPC, ADP YPP.

  20. Iseju díẹ̀ ló kù

    Gbongan WAEC International ni a wá ní Ikeja Ìpínlẹ̀ Èkó.