You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.

Take me to the main website

Ìròyìn ìbúrawọlé jákèjádò orílẹ̀èdè Nàìjíríà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.

Aarẹ Muhammadu Buhari, igbakeji rẹ, awọn gomina ipinlẹ ati awọn igbakeji wọn ni wọn bura fun lonii

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Yetunde Olugbenga and Busayo Akogun

  1. Ẹgbẹ́ awọn ẹlẹṣin naa le tente sibi ibura gomina Ọyọ

    Awọn ẹgbẹ ẹlẹṣin naa ko gbẹyin ni papa iṣere Liberty Stadium nibi ayẹyẹ iburawọle gomina tuntun nipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde.

  2. Buhari gba àsìá orilẹede Naijiria tuntun

    Ọga agba ileeṣẹ ologun, Abayọmi Ọlọniṣakin gbe asia tuntun fun Aarẹ Muhammadu Buhari lẹyin to bura tan lati ṣi ilẹkun fun saa iṣejọba tuntun.

  3. Òjò wọ̀ọ̀ wọ̀ọ̀ ní gbàgede ètò ìbúrawọlé ti Abeokuta

    Bi awọn araalu ṣe n reti ki iburawọle bẹrẹ ni ipinlẹ Ogun ni ojo bẹ silẹ fun o fẹrẹ to wakati kan ni gbagede MKO Abiola ti eto iburawọle ti n waye.

  4. Ààrẹ tọwọ́ bọ̀wé níwájú adájọ́

  5. Ẹ le maa wo bi ibura ṣe n lọ lori Facebook wa

  6. Eyi ni bi Aarẹ Buhari ṣe de si gbagede Eagles Square

  7. Aarẹ Buhari burawọle fun saa keji

    "Mi o ni jẹ́ ki ifẹ́ inu ara mi tabuku ba ifẹ́ iṣẹ́ ilu". Eyi wa lara ọrọ iburawọle aarẹ Muhammadu Buhari.

    Aarẹ ni oun yoo maa ṣe ni ibamu pẹlu ofin ajọ to n boju to ọ̀rọ̀ dukia awọn to di ipo nla mu lawujọ, Code of Conduct Bureau... "Ki oluwa ki o ran mi lọ́wọ́"

  8. Oluwo ti ilu Iwo, Emperor Abdulrasheed Akanbi, ati olori rẹ naa ba wọn kopa nibi iburawọle l'Abuja.

  9. Ọṣinbajo buwọlu iwe lẹyin iburawọle

  10. Bukọla Saraki ati Yakubu Dogara kopa nibi ibura Buhari

    Aarẹ ile aṣofin agba Naijiria, Sẹnetọ Bukọla Saraki ati Olori ile igbimọ aṣojuṣofin, Yakubu Dogara naa darapọ mọ ọpọlọpọ eniyan to kopa nibi ayẹyẹ iburawọle saa keji fun Aarẹ Buhari ati igbakeji rẹ ni gbagede Eagles Square.

  11. Bó ṣe n lọ ni ìpínlẹ̀ Kwara

    Gomina tuntun ni Kwara, Abdulraman Abdulrazaq ati iyawo rẹ nibi ayẹyẹ iburawọle.

  12. Ọṣinbajo burawọle gẹgẹ bi igbakeji aarẹ fun saa keji

    Adajọ agba nile ẹjọ to ga ju ni Naijiria, Tanko Muhammad bura fun igbakeji aarẹ, Yẹmi Ọṣinbajo.

  13. Àdúrà ìbẹ̀rẹ̀ ní Eagles Square Abuja

    Imam agba fun mọṣalaṣi gbogboogbo nilu Abuja, Ọjọgbọn Shehu Galadanci, ati Aarẹ ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi, Ẹni Ọwọ Ṣupọ Ayọkunle lo gba adura ibẹrẹ ni gbagede Eagles Square Abuja fun iburawọle Aarẹ Muhammadu Buhari ati Igbakeji rẹ, Yẹmi Ọṣinbajo.