You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.

Take me to the main website

Sáà kéji tọ́ sí Buhari - Asíwájú Bola Tinubu

A ń mú ìsẹ̀lẹ̀ bó se ńlọ lọ́wọ́lọ́wọ́ níbi ìdálọ́lá Olóògbé MKO Abiola ní Abuja àti ètò ìràntí ìgbà àyé rẹ́ tó ń wáyé káàkiri ẹkùn Gúúsù-Iwọ̀ Oòrùn Nàìjíríà.

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Yetunde Olugbenga

  1. Wọ́n de àwọn ènìyàn lọ́nà àti wọlé Abiọla

    Ń se ni ìta ilé olóògbé Moshood Kashimawo Ọlawale (MKO) Abiọla kún pitimu fún onírúurú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ẹni, tí wọn máa ń wá se ìrántí rẹ̀ ní àyájọ́ ọjọ́ kejìlá osù kẹfà ọdọọdún. Sùgbọ́n fún ìyàlẹ́nu, wọn kò jẹ́ kí wọn wọlé nítorí àwọn gómìnà mẹ́rin ló ń bọ̀ wá lọ́dún yìí láti wá se ìrántí náà

  2. Ìyàwó àti ọmọ Gani dunú bí wọ́n se dé Aso Villa

    Àwọn mìíràn tí yóò gba oyè ìdálọ́là pẹ̀lú MKO Abiola (GCFR) ni Gani fawehinmi (GCFR) àti Baba Gana- Kingibe (GCON) lónìí.

    Ìròyìn tó ń tẹ̀ wa létí sọpé ìyàwó àti àkọ́bí ọmọkùnrin Olóyè Gani Fawẹhinmi, Ganiyat pẹ̀lú Mohammed ti gúnlẹ̀ sí ilé ìjọba, Aso Villa níbi tí ìdálọ́lá náà yóò ti wáyé.

    Mohammed sọ fún àwọn akọ̀ròyìn ilé ìjọba pé inú òun dùn pe ìlàkàkà Bàbá òun kò já sásán.

  3. Àwòràn ibojì MKO Abiola

    Akọ̀ròyìn wa wà ní ilé Olóògbe MKO Abiola ní agbègbè Allen, Ikeja ìlú Eko lọ́wọ́lọ́wọ́. Yóò máa fi ìròyìn bó se ń lọ sọwọ́ sí wa lórí ìtàkùn yìí.

    Lára àwọn àwòrán tó yà níbi ètò tó ń lọ ní sàréè rẹ̀ nìyìí.

  4. Ta ni MKO Abiola?

    Olóyè Moshood Kashimawo Olawale Abiola jẹ́ ọmọ Yorùbá, ọmọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà, onísòwò, òǹkọ̀wé, olósèlú àti ajàfẹ́tọ́ọ́ ọmọnìyàn.

    A bí i ní ọjọ́ kẹrìnlélógún osù kẹj ọdún 1937 ní ìlú Abẹokuta.

    Ó du ìpó Ààrẹ nínú ìdìbò ọdún 1993 lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òsèlú SDP, ó wà ní bèbè jíjáwé olúborí nígbà tí wọ́n fagilé ìbò náà.

    MKO Abiola re 'bi àgbà ń rè ní ọjọ́ keje, osù keje ọdún 1998.

  5. Ẹ kú ojúmọ́ gbogbo ọmọ káàrọ̀ o jíire, a kíi yín káàbọ̀ sórí BBC Yorùbá Live. Àkọ́já ewé ni èyí lórí ìtàkùn bbc.com/yoruba.

    Orúkọ́ mi ni Yetunde Olugbenga. Èmi ni n ó máa mú ìròyìn bó se ń lọ́ lónìí tíí se àyájọ́ June 12 káàkiri orílẹ̀èdè Nàìjíría.