Nigeria's Under-19: Ẹ wo bí Ikọ̀ Cricket Naijiria ṣé mí àgbáyé titi

Àkọlé fídíò, Nigeria's Under-19:Ẹ wo bí Ikọ̀ Cricket Naijiria ṣe mi àgbáyé titi
Published

Ikọ agbabọọlu ere alafigigba ta mọ si Cricket lọrilẹede Naijiria ti ni o da bi ala loju awọn pẹlu bi awọn ṣe pegede lati kopa ninu idije Ife Agbaye Cricket fun igba akọkọ.

Lorileede South Africa ni idije fawọn ọjẹwẹwẹ ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun mọkandilogun lọ naa ti o ti gbera sọ lọjọ kọkanlelogun oṣu kini ti n waye.

Balogun Ikọ naa lasiko to n ba BBC sọrọ ni idunnu ati ayọ lọ jẹ fun awọn pe awọn ṣe aṣeyọri latyi kopa ninu idije naa bi o tilẹ je pe awọn eniyan ko fi taratara gba ti ere idaraya ọhun.

Naijiria yoo ma a koju ikọ Australia ninu ipele akọkọ fun idije agbaye naa.

Peter Aho to ṣẹṣẹ pe ẹni ọdun mẹrindinlogun lo gba bọọlu wọnu awọn ti wọn fi bori ifẹsẹwọnsẹ ti wọn fi jawe olubori patapata.

Awọn ọmọ ikọ Agbabọọlu Cricket Naijiria ni awọn sa ipa awọn ki awọn le jẹ iwuri fun ikọ ojẹwẹwẹ to n bọ lọna.

Wọn fi kun pe awọn ni igbagbọ pe awọn eniyan yoo bẹrẹ si ni fẹran lati ma a wo ẹrẹ bọọlu Cricket naa bi wọn ti ṣẹ fẹran ẹrẹ bọọlu afẹsẹgba.