Iná ṣẹ́yọ níléeṣẹ́ tẹlifíṣàn BCOS Ibadan, ọ̀pọ̀ ohun èlò igbóhùnsáfẹ́fẹ́ ṣòfò

Published

Ni nnkan bii aago meji ọsan ku ogun iṣẹju lọjọru ni awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ amohun-maworan BCOS to n bẹ lagbege Baṣọrun nilu Ibadan ṣe akiyesi eefin ina to n tu jade lati inu ọkan ninu awọn iyara ti wọn ti n ka ohun silẹ ki wọn to fi si ori afẹfẹ.

Iyara naa ni iroyin sọ pe wọn ti maa n gba ohun silẹ fun akanṣe eto 'Ṣo daa bẹẹ?' ki o to di pe eto naa yoo gun ori afẹfẹ.

Ohun to mu ki ina naa fẹju kan ki awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọhun to ṣe akiyesi rẹ ni pe iyara igbohunsilẹ naa kii ṣe ibi ti wọn saba maa n lo ni gbogbo ọjọ.

Lọgan ti eefin ina naa ru sita ni gbogbo awọn oṣiṣẹ sa kuro ninu ile igbohunsafẹfẹ ti wọn si ko ara jọ pọ si gbagede ti wọn n ko ọkọ si ninu ọgba ileeṣẹ naa.

Lẹyin asiko diẹ ti ina naa bẹrẹ si n jo ni awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana ti ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ fi ara han ti wọn si pa ina naa.

Ọkanojọkan awọn ẹṣọ aabo naa ko gbẹyin ninu ọgba ileeṣẹ ọhun.

Botilẹ jẹ wi pe ẹnikẹni ko fi ara pa ti ẹmi kankan ko si ba iṣẹlẹ naa lọ, ọpọ ohun elo ti wọn fi n gba ohun silẹ fun awọn akanṣe eto lo jona raurau.