You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àìtẹ̀lé ìlànà òfin la ṣe wó ilé iṣẹ́ tí Gbenga Daniel ń kọ́ ní Ijebu Ode - Ìjọba Ogun
Ní bí ọjọ́ mẹ́ta sẹ́yìn ni ìròyìn ń jà ràìnràìn lórí bí ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun ṣe dá ilé iṣẹ́ kan tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́ wó ní ìlú Ìjebu Ode, ìpínlẹ̀ náà.
Ilé tí ìjọba dà wó náà ló ti ń fa onírúurú awuyewuye nítorí wọ́n ní gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ ọ̀hún, Gbenga Daniel ló ni ilé náà.
BBC Yorùbá kàn sí ìjọba ìpínlẹ̀ láti gbọ́ kúlẹ̀kúlẹ̀ ìdí tí ìjọba fi gbé ìgbésẹ̀ tó gbé láti da ilé náà wò.
Abimbola Abiodun tó jẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọ ní ẹ̀ka ilé iṣẹ́ ìjọba ṣàlàyé àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ilé kíkọ́ náà kò tẹ̀lé ìlànà àti òfin tí ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun là kalẹ̀ nípa ilé kíkọ́ ni ìjọba fi da ilé náà wá.
Abiodun ní láti ọdún tó kọjá ni àwọn ti kọ́kọ́ ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn tó ń kọ ilé iṣẹ́ náà pé wọn kò gbàwé àṣẹ tó yẹ kí wọ́n tó máa ka ohunkóhun síbẹ̀.
Ó tẹ̀síwájú pé yàtọ̀ sí pé wọn kò gbàwé àṣẹ tó yẹ, ó ní ohun tí wan kọ sínú ìwé pé àwọn máa kọ sórí ilẹ̀ náà yàtọ̀ sí àwọn nǹkan tí wọ́n ń kọ́.
Ó ní ìdí nìyí ti ìjọba fi dìde láti wo ilé iṣẹ́ náà.
Bákan náà ló fi kun pé àwọn k]o tilẹ̀ mọ ẹni tó ni ilé ọ̀hún tí àwọn fi ṣe iṣẹ́ ti tàwọn nítorí ìrọ̀rùn ará ìlú ni àwọn ń fẹ́ .
Láti ọdún 2009 ni a ti gba ìwé àṣẹ - Alámójútó ilé iṣẹ́ tí wọ́n dà wó
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀, onímọ̀ ẹ̀rọ tó jẹ́ alámòójútó ilé iṣẹ́ tí wọ́n dà wó náà ṣàlàyé pé láti ọdún 2009 ni wọ́n ti gba àṣẹ láti ilé eṣẹ́ tó ń mójútó ààtò ìlú láti kọ ilé alájà mẹ́rin sí àdúgbò náà.
Lawal ní nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ wá ti ilé iṣẹ́ náà pa ni àwọn ti kó gbogbo àwọn ìwé àṣẹ tí àwọn gbà han ìjọba.
Ó ṣàlàyé pé lẹ́yìn náà ni àwọn lọ san owọ láti fi sọ fún wọn pé kí wọ́n ṣí ilé náà padà.
Ó nílẹ́yìn tí àwọn san owó náà tán ni ìjọba wá da ilé náà wò tí àwọn kò sì mọ̀ pé nǹkan tí ìjọba fẹ́ ṣe nìyẹn.