Báwo ni ìdìbò Claudia Sheinbaum gẹ́gẹ́ bí ààrẹ obìnrin àkọ́kọ́ yóò ṣe dẹ́kùn ọwọ́jà ìpànìyàn lórílẹ̀èdè Mexico?

Claudia Sheinbaum

Oríṣun àwòrán, Reuters

Published

Claudia Sheinbaum ti wọle ibo gẹgẹ bi obinrin akọkọ ti yoo di ipo aarẹ mu lorilẹede Mexico.

Ajọ eleto idibo lorilẹede Mexico kede peida mejidinlọgọta si mọkanlelọgọta ibo ti wọn di lọjọ Aiku ni Arabinrin Sheinbaum fi bori.

Eyi tumọ si pe nnkan bii ida ọgbọn ninu ọgọrun lo fi n lewaju alatako rẹ, ti oun pẹlu jẹ obinrin, iyẹn gbajumọ oniṣowo Xóchitl Gálvez.

Arabinrin Sheinbaum yoo maa gba ipo lọwọ Aarẹ Andrés Manuel López Obrador ti yoo fi ipo silẹ ni ọjọ kinni oṣu kẹwaa ọdun 2024.

Eto idibo naa ninu eyi ti o ti jẹ pe awọn obinrin meji lo n fi ori gbari ni ọpọ lorilẹede naa ti tọka si gẹgẹ bii afẹfẹ ọtun lagbo oṣelu orilẹede Mexico.

Yatọ si yiyan aarẹ, awọn oludibo ni Mexico tun dibo yan awọn aṣofin, awọn gomina ipinlẹ mẹjọ, olori ijọba ilu Mexico ati ọkẹ aimoye awọn oloṣelu ijọba ibilẹ.

Wahala ati ikọlu wọpọ lasiko idibo naa

Awọn ibọn ati ogun oloro

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Pẹlu bi o ṣe jẹ pe awọn obinrin meji ni oludije to lamilaaka julọ lasiko idibo naa, sibẹ iwa jagidijagan, wahala ati ikọlu loniraanran.

Ijọba orilẹede naa ni o le ni ogun eeyan ti wọn padanu ẹmi wọn jakejado orilẹede Mexico, bi o tilẹ jẹ wipe awọn onka kan n sọ pe wọn le ni mẹtadinlogoji.

Gẹgẹbi ohun ti awọn onwoye n sọ, eto idibo yii lo ṣi la wahala ati itajẹsilẹ to pọ julọ lọ ninu ita oṣelu orilẹede Mexico.

Bawo ni Aarẹ Claudia yoo ṣe koju iwa ipa ni Mexico?

Awọn ero lẹyin ti wọn kede idibo ni Mexico

Oríṣun àwòrán, EPA

Bi yoo ṣe koju gulegule awọn ẹgbẹ agbebọn ni yoo jẹ olubori ipenija ti Claudia Sheinbaum koju lasiko saa rẹ gẹgẹ bi aarẹ Mexico.

O ti sọ ọ ṣaaju pe o ṣe pataki lati kọkọ gbogun ti ohun to pe ni okunfa iwa ipa lorilẹede naa, to si tun ṣeleri lati ko owo jade si oro awọn eto ba-n-tan’ṣẹ lati mu ki awọn ọdọ to ku diẹ kaa to fun lorilẹede naa bọ lọwọ awọn to n fi owo tan wọn wọ ẹgbẹ agbebọn ati agbenipa gbogbo.

Arabinrin Sheinbaum ni ireti oun ni lati din ọwọja iwa ipaniyan lorilẹede naa ku nigba ti a o ba fi ri ọdun 2027.

O tọka si asiko to fi jẹ olori ijọba ilu Mexico eyi ti wọn ti ni ọwọja iṣẹlẹ ipaniyan dinku pẹlu ida aadọta ninu ọgọrun (50%).

Bakan naa lo ni oun yoo mojuto ajọṣepọ laarin orilẹede Mexico ati Amẹrika eleyi to ti dẹnukọlẹ lati bi ọdun diẹ sẹyin.