Ṣé lóòtọ́ ni ṣọ́jà kan yìnbọn pa ara rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun?

Oríṣun àwòrán, Google
Ṣọja kan, Boyi ThankGod, ni iroyin sọ pe o yinbọn pa ara rẹ lọjọ Mọnde ọsẹ yii niluu Abẹokuta.
Eyi waye lẹyin ẹsun ti wọn lo fi kan ileeṣẹ ologun pe wọn ko tọju awọn ṣọja, ati pe ajẹbanu ati ẹtan pọ nidii iṣẹ ọhun.
Barake ologun 81 Division, 35 Artillery to wa l’Alamala, niluu Abẹokuta ni Oloogbe ThankGod n ba ṣiṣẹ nigba aye rẹ.
O darapọ mawọn ologun to yan fanda layajọ ologun to ṣubu loju ija ni Mọnde ọsẹ yii, ṣugbọn wọn lo pẹ to ti maa n sọ pe iṣẹ ologun ti su oun.
Awọn ọrẹ ThankGod sọ fawọn akọroyin, pe airowo gidi gba lẹnu iṣẹ ti fa iporuru ọkan fun oloogbe naa tipẹ.
Wọn lo ti maa n sọ ọ pe oun yoo fiṣẹ naa silẹ nitori ko si iwuri nibẹ, bẹẹ ni ẹtan pọ latoke wa.
Ori ni wọn ni ṣọja to doloogbe yii doju ibọn rẹ kọ lọjọ to ṣetan ati gbẹmi ara rẹ, ẹsẹkẹsẹ to si yin in lo dagbere faye ninu agbara ẹjẹ.
Ki lohun ti ileeṣẹ ologun sọ lori iku naa?

Oríṣun àwòrán, Google
Adele agbẹnusọ awọn ṣọja nipinlẹ Ogun, Lieutenant Colonel Ọlabisi Ayẹni, ṣalaye ninu atẹjade rẹ to fi sita l’ Ọjọru, pe isọkusọ lawọn to ni ṣọja naa para rẹ nitori owo n sọ kiri.
Ayẹni sọ pe, ‘’Ṣọja to doloogbe yii wa lara awọn ta a ni ki wọn lọ si gbagede ta a ti ṣeranti awọn ologun to ku soju ija lọjọ Mọnde, gbogbo wọn la si ṣeto to yẹ fun ki wọn too lọ.
‘’ Iwadii fi ye wa pe ijafara, ailakiyesi lo fa iku naa. Ibọn rẹ ṣeṣi yin mọ ọn latari aikiyesara ni.
‘’ Awọn ẹlẹgbẹ ẹ to gburoo ibọn sare lọ sibẹ, ṣugbọn inu agbara ẹjẹ ni wọn ba a pẹlu ọgbẹ́ lori rẹ’’
Ọga ṣọja naa tẹsiwaju pe bi ThankGod ṣe ku ṣi n jẹ ibanujẹ fun ileeṣẹ ologun Ogun, o lo buru jai bawọn kan ṣe tun n fiṣẹlẹ naa ba awọn lorukọ jẹ.
Iwadii ṣi n tẹsiwaju b’Ayẹni ṣe wi, bẹẹ lo ni oku ṣọja naa ti wa ni mọṣuari ileewosan FMC, l’Abẹokuta.

























