Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́ - 30, Owewe, 2024

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́ - 30, Owewe, 2024
Published

Ileeṣẹ ọlọpaa ti fi ṣikun ofin mu obinrin kan, Khadija Aliyu, lori ẹsun pe o ji ọmọ ọjọ meje kan gbe lọjọ isọmọlorukọ rẹ

A gbọ pe ṣe ni obinrin naa dibọn bii alaboyun, to si fi ọgbọn alumọkọrọyi wọ inu ile ti isọmọlorukọ ọhun ti n waye lati ji ọmọ naa gbe nibi to sun si

Nibo wa ni iṣẹlẹ naa ti waye, ati pe bawo ni ọwọ ọlọpaa ṣe afurasi ọhun?

Kan soju opo BBC Yoruba fun ẹkunrẹrẹ

Nilẹ Amẹrika

Eeyan to le lọgọrun lo ti jade laye nigba ti ọpọ awọn mii di alairilegbe ni lẹyin iji lile Hurricane Helene to ṣọṣẹ nibẹ

A gbọ pe ọgbọn eeyan lo ku lagbegbe kan sọsọ nipinlẹ North Carolina

Lọwọ yii, nnkan bii ẹgbẹrun kan eeyan ni wọn ṣi n wa lẹyin iṣẹlẹ ọhun

To ba fẹ mọ bo ṣe n lọ