Kò dìgbà tí a bá búra wa kí a tó kọrin tó dùn - Ààrẹ Shina Akanni

Gbajúmọ̀ olórin Fuji nnì, Ààrẹ Shina Akanni ti rọ gbogbo àwọn onifuji bi tirẹ̀ láti máa fi ìfẹ́ bá ara wọn lò.
Akanni nígbà tó ń bá BBC News Yorùbá sọ̀rọ̀ ní Ọba ìlú Mushin ló fi òun jẹ ààrẹ kí olóògbé Barrister tó jan orúkọ náà lóǹtẹ̀ fún òun.
Ó ṣàlàyé àwọn èèkàn nídìí iṣẹ́ tí òun yàn láàyò bíi Barrister, Alhaji Kollington Ayinla, Wasiu Ayinde ni òun wò kọ́ṣe tí òun fi dé ibi tí òun wà lónìí.
Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ni òun kọ́ lára àwọn èèkàn náà.
Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé onírúurú ìpèníjà ni òun kojú nígbà tí òun ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àmọ́ òun máa ń ri dájú pé òun fi ìfẹ́ lò pẹ̀lú gbogbo àwọn tí àwọn jọ jáde sí àsìkò náà.
Ó fi kun pé kò dìgbà tí àwọn bá búra àwọn kí àwọn tó lè kọrin àti pé àwọn olólùfẹ́ àwọn nílò láti gbádùn orin gidi yàtọ̀ sí gbígbọ́ èábú ní gbogbo ìgbà.
Olórin Fuji náà tún ṣàlàyé ipa tó kó lásìkò tí àwọn gbajúmọ̀ olórin Fuji méjì nnì Pasuma àti Saheed Osupa ń fa wàhálà láàárín ara wọn.
Ó ni gbogbo ìgbà ni òun máa ń pẹ̀tù sí wọ́n nígbà náà àti pé òun kò ní olódì ẹnìkan ní agboolé Fuji.
Ó wá rọ gbogbo àwọn olófin Fuji láti àwòkọ́ṣe àwọn àgbààgbà olórin, èyí tó wà láyé àti àwọn tó ti papòdà láti máa ṣe àtọ́nà irinàjò wọn.






