Kò ṣeé má gbọ̀ọ́
Gbọ na, ta lo gbe Adura Aloba, to jẹ aburo Mohbad to di oloogbe lọ ni kootu?
Ah, wọn gbe aburo Mohbad kẹ? Awọn wo? Nibo? Nigba wo?
Iroyin ni agbegbe ile ẹjọ Majisreeti to wa ni Ogba, nipinlẹ Eko ni awọn to gbe Adura ti gbe e
Ayeo o!
Yatọ si Adura, a tun gbọ pe wọn gbe ọrẹ rẹ kan rẹ Ibrahim Koleosho ti wọn n pe ni (King White) naa lọ
Ẹkunrẹrẹ wa loju opo wa
_______________________________________
Olori ẹgbẹ ajijagbara IPOB, Nnamdi Kanu ti sọ pe oun ko jẹbi ẹsun igbesunmọmi ti ijọba Naijiria fi kan oun
Kanu lo sọ bẹẹ ni bayii ti igbẹjọ ẹsun ti ijọba fi kan bẹrẹ lakọtun
Lati ọdun 2015 ni ijọba Naijiria ti n ba Kanu ṣe ẹjọ ko to sọ pe oun ko fẹ adajọ to n gbọ ẹjọ oun mọ
________________________________________
Nilẹ Gẹẹsi
Wọn ti gbe papakọ ofurufu Heathrow, to wa niluu London tipa lẹyin ina kan to ṣẹyọ nibẹ
Yatọ si awọn ọkọ ofurufu ti ko ni fo
Wọn tun wọgile awọn irinajo ọkọ oju irin to wa lagegbe papakọ ofurufu ọhun
Fun ẹkunrẹrẹ