Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Iya ijọ ko si ahamọ ọlọpaa lẹyin ti iya ati ọmọ tuntun ku si ile ijọsin lasiko igbẹbi
Haaa, Ikunlẹ abiyamo, ki lo ṣẹlẹ
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo lo fidi iroyin naa mulẹ ni ẹjẹ ni ko da lara obinrin naa lẹyin to bimọ
Ṣe iya ijọ naa kii ṣe agbẹbi ni?
Kan si oju opo BBC.com fun ẹkunrẹrẹ
Lorilẹede Amẹrika, Donald Trump ti yan oludasilẹ ikanni X, Elon Musk sipo alamojuto atunto ati ijafafa iṣejọba l’Amẹrika
Yatọ si Musk, Trump tun yan Vivek Ramaswamy, ti oun naa jẹ baba olowo gọbọi lati maa ba Musk ṣiṣẹ papọ.
Bisọọbu agba ijọ Canterbury ilẹ Gẹẹsi kan ree to kọwe fipo rẹ silẹ
Laduru ipo banta banta yẹn, ki lo de?
Alufaa abẹ rẹ kan, John Smith ni wọn fẹsun kan pe o ṣe aṣemaṣe pẹlu awọn ọmọdekunrin lọdun 2013.
Ki wa ni tirẹ nibẹ?
O ni oun gbagbọ pe ki oun fipo silẹ ni ohun to tọ bayii, paapaa fun ijọ ilẹ Gẹẹsi.
