Ìpínlẹ̀ Oyo pàdánù rẹfirí méjì láàrín ọjọ́ méjì

Aworan awọn rẹfiri mejeeji

Oríṣun àwòrán, others

Published

Igbimọ iṣakoso bọọlu alafẹsẹgba nilẹ Ibadan, 'Ibadan Football Council(IFC)' ti fi ọrọ ibanikẹdun ranṣẹ si ẹgbẹ awọn adari ifẹsẹwọnsẹ n'ipinlẹ Ọyọ, lori iku eeyan meji lara ọmọ ẹgbẹ wọn.

Awọn adari ayọ to papoda naa ni Ibikunle Abiodun ati Rafiu Kazeem Opeyemi lati ijọba ibilẹ Akinyele ati Ona-Ara.

Awọn mejeeji jade laye laarin wakati mẹrinlelogun si ara wọn

Iroyin fi idi rẹ mulẹ wi pe Abiodun jẹ Ọlọrun nipe lọjọ Ẹti lẹyin aisan ranpẹ, nigba ti Kazeem Opeyemi padanu ẹmi rẹ nibi ijamba ọkọ ti o waye lọjọ Abamẹta ni opopona ilu Oṣu n'ipinlẹ Ọṣun lasiko to n bọ lati ibi ayẹwo ikojuosunwọn ti o lọ ṣe nilu Abuja.

Awọn adari ayo meji mii Segun Oni ati Ajadi Odunayo to fi ara pa ninu ijamba ọkọ naa ti gba itọju nile iwosan, wọn si ti pada sile wọn.

Alaga igbimọ iṣakoso bọọlu alafẹsẹgba nilẹ Ibadan, Mogaji Rotimi Alli fi ibanujẹ ọkan han ninu iwe ibanikẹdun to buwọlu lorukọ igbimọ naa.

O gbadura si Ọlọrun lati dawọ iru iṣẹlẹ aburu bẹẹ duro ninu ẹgbẹ naa ati ninu ẹgbẹ bọọlu alafẹsẹgba jakejado orilẹede Naijiria, gẹgẹ bi o ṣe gbadura pe ki Ọlọrun tu mọlẹbi awọn oloogbe ninu.

Awọn akọroyin ere idaraya pẹlu kẹdun

Bakan naa ni ẹgbẹ awọn akọwe iroyin ere idaraya n'ipinlẹ Ọyọ, 'Sports Writers Association of Nigeria (SWAN)', fi ibanikẹdun wọn ranṣẹ si ẹgbẹ awọn adari ifẹsẹwọnsẹ n'ipinlẹ Ọyọ ati awọn ẹgbẹ bọọlu alafẹsẹgba lori iṣẹlẹ ojiji ti o mu ẹmi awọn adari ayọ meji lọ lopin ọsẹ.

Ninu iwe ibanikẹdun ti alaga ẹgbẹ naa, Niyi Alebiosu kọ, ti akọwe ẹgbẹ, Adewale Tijani buwọlu, ẹgbẹ naa kẹdun pẹlu mọlẹbi awọn oloogbe ati awọn igbimọ iṣakaso ifẹsẹwọnsẹ n'ipinẹ Ọyọ lori iṣẹlẹ aburu naa.

Wọn fi kun ọrọ wọn wi pe ọjọ buruku gbaa ni ọjọ ti wọn padanu mẹji ninu awọn ọmọ ẹgbẹ wọn lai ro tẹlẹ, pẹlu alaye wi pe adanu nla ni ipapoda awọn mejeeji jẹ fun igbimọ bọọlu alafẹsẹgba ati ẹgbẹ awọn akọwe iroyin ere idaraya n'ipinlẹ Ọyọ ati lorilẹede Naijiria.

Awọn aṣoju ẹgbẹ naa ke si awọn igbimọ iṣakoso ere idaraya n'ipinlẹ Ọyọ lati ṣe ifilọlẹ awọn nnkan manigbagbe lorukọ awọn oloogbe naa, ki iranti awọn ipa ribiribi ti wọn ko fun idagbasoke ere idaraya ma baa parun.

Wọn gbadura pe ki Ọlọrun tu mọlẹbi awọn oloogbe ninu, ki o si ṣẹwọ iru iṣẹlẹ bẹẹ mọ laarin wọn n'ipinlẹ Ọyọ ati lorilẹede Naijiria.