Ọ̀pọ̀ egúngún yabo mọ́sálásí, lu ìyàwó Imam agba, ọmọ rẹ, ọ̀rọ̀ di bóò lọ yàgò l'Ondo

Ọrọ di ẹni ori yọ, o dile bi ọpọlọpọ egungun se yabo mọsalasi ati ile Imam agba ilu Oke Agbe, Akoko, nijọba ibilẹ Ariwa Akoko nipinlẹ Ondo.
Awọn Eegun yii lu awọn ọmọ Imam agba naa ati aya rẹ ni alubami ni ọsẹ to kọja.
Ẹgbẹ to n ja fẹtọ awọn ẹlẹsin Islam, MURIC, ti wa gbarata lori iṣẹlẹ naa, to si bẹnu atẹ lu iṣẹlẹ yii, ti wọn si ri gẹgẹ bi ikọlu si ẹṣin islam.
MURIC sọ pe akọlu yii tun safihan okanjọkan awọn akọlu ati inunibini si ẹṣin Islam ni ilẹ Yoruba.
O wa ke si ijọba lati gbe igbese ti o tọ, ki wọn si fi panpẹ ọba mu awọn to huwa ibi yi.
Ẹgbẹ naa, ninu atejade to fi lede, seleri lati tọpinpin ọrọ naa titi ti idajọ ododo yoo fi waye lori rẹ.
BBC Yoruba gbiyanju lati ba Imam agba naa sọrọ lati mọ bi iṣẹlẹ yi ṣe waye, wọn fidi rẹ mulẹ pe ootọ ni akọlu naa waye, sugbọn wọn lọra lati salaye isẹlẹ naa lẹkunrẹrẹ.
Imam agba naa sọ fun BBC Yoruba pe ọrọ naa ti wa lọdọ awọn olori ilu Oke Agbe Akoko.
Igbimọ Alfa ati Imaamu fun àwọn ọlọpaa ni ọsẹ meji lati se awari awọn eegun to na aya ati ọmọ Imaamu agba
Nibi ipade pajawiri ti agbarijọpọ igbimọ awọn Alfa àti Imam ni agbegbe Akoko ṣe, wọn koro oju si iwa aitọ ti awọn onisẹse naa hu.
Wọn ni iwa naa buru jai.
Igbimọ naa kesi Oluawo ilu Oke Agbe Akoko, lati rawọ ẹbẹ si gbogbo Musulumi ilu naa to fi mọ Imam agba ati mọlẹbi rẹ.
Awọn Imam naa kesi awọn ẹsọ alaabo lati gbe igbesẹ to yẹ lori ọrọ naa, ki wọn fi panpẹ ọba mu awọn kọlọransi naa ati awọn to ran wọn.
Ipade naa fun ijọba ati awọn ẹsọ alaabo ni gbendeke ọsẹ meji lati gbe awọn igbesẹ ti o tọ, bi bẹẹ kọ, wọn yoo gbe igbesẹ to lagbara lori ọrọ naa.
Kíni Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá sọ?
Alukoro ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Ondo Olusola Alayande sọ pe, Kọmisọna Ọlọpaa Wilfred Afolabi tí pasẹ fun DPO ileeṣẹ Ọlọpaa ilu Oke Agbe Akoko lati pari aawọ to waye naa.
Lasiko to n ba BBC YORUBA sọrọ, Alayande sọ di mimọ pe awọn alasẹ ilu Oke Agbe Akoko yan lati pari ija to waye laarin awọn oniṣẹṣe ati awọn musulumi naa laarin ara wọn.
O sọ pe DPO ileeṣẹ Ọlọpaa ilu naa si darapọ mọ wọn lati le pari aawọ yi.
Alukoro naa sọ pe Kọmisọna Ọlọpaa Ipinlẹ Ondo ti kilọ fun gbogbo ẹlẹsin lati se isin wọn lọna to bofinmu nitori Ipinlẹ Ondo ko ni faye gba irufẹ iṣẹlẹ yi lawujọ.
O kilọ pe enikeni to ba fi ọwọ pa ida ofin yoo fẹnu fẹra bi abẹbẹ


























