Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fásitì EKSU rawọ́ ẹ̀bẹ̀ síjọba láti ṣí ojú òpó ilé ẹ̀kọ́ náà fún ìforúkọsílẹ̀

Ita ilé ẹ̀kọ́ EKSU, Ado Ekiti

Oríṣun àwòrán, Gmartnews

Published

Awọn akẹkọọ ile ẹkọ Fasiti ipinlẹ Ekiti (EKSU) ti rawọ ẹbẹ si awọn adari ile ẹkọ naa lati ṣiju aanu wo ọpọlọpọ awọn ti wọn ko i tii san owo ile ẹkọ wọn ki o to di wi pe oju opo naa di titipa

Awọn akẹkọọ naa ni pe kii ṣe wi pe awọn ko fẹ san owo naa amọ oju opo ayelujara ile ẹkọ naa to n ṣe ṣegeṣege ni ko jẹ ki awọn ri owo naa san.

Adari ẹka to n ri si ọrọ awọn akẹkọọ ni ile ẹkọ naa, Ọjọgbọn O.O. Omotoso ni o gbe ọrọ naa lọ ọdọ awọn aṣofin ile ẹkọ ọhun lati le fi oju aanu wo awọn akẹkọọ ti ọrọ naa kan.

Ni ọjọ Kẹrinlelogun, oṣu Kẹfà ni ijokoo ipade naa kọkọ waye ṣugbọn ipade naa ni ko fi oju aanu wo awọn akẹkọọ naa lati le ni anfaani ati se iforúkọ wọn silẹ ni oju opo Fasiti naa.

Abọ ipade naa lo ni ki awọn akẹkọọ ti ọrọ naa kan ko lọ duro fun saa to n bọ ati pe ki wọn lọ kọ lẹ́tà si awọn adari Fasiti naa nitori wọn ti fun wọn lọjọ kun ọjọ ati le ṣe ohun to yẹ lati ṣe ṣugbọn ti wọn kuna lati ṣe bẹẹ.

Eyi ni abọ ipade ti Ọjọgbọn O.O. Omotoso ba bọ lati ẹnu awọn asofin ile Ẹkọ Fasiti naa.

Awọn akẹkọọ ti ọrọ naa kan tun ke gbajare lọ sọdọ ijọba Ìpínlẹ̀ Ekiti lati le bawọn dasi ọrọ naa bayii.

Awọn akẹkọọ naa n rọ ijọba lati ba awọn pàrọwà si awọn adari Fasiti naa lati le fi oju aanu wo awọn, ki wọn le ṣi oju opo naa fun awọn pada lati le sanwo ati forukọ silẹ fun saa eto ẹkọ naa.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọkan lara awọn akẹkọọ ti ọrọ naa kan ti o ba akọroyin BBC News Yoruba ṣọrọ amọ ti ko fẹ ka darukọ oun ni ọpọlọpọ awọn ti san owo ki o to di wi pe oju opo naa di titipa, to si jẹ wi pe oju opo ayelujara ni ko ṣe daadaa ni ko jẹ ki owo naa tete bọ sinu aṣuwọn ile ẹkọ awọn ti o si jẹ wi pe ti owo ko ba bọ si apo owo ilé ẹkọ naa, wọn ko le tẹsiwaju ninu iforukọ naa silẹ.

Ninu ọrọ rẹ, alaga ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ti kii ṣe olukọ ni ile ẹkọ Fasiti ipinlẹ Ekiti, SSANU, ọgbẹni Aguda Temidayo Azeez tun parọwa si awọn adari ile ẹkọ lati boju aanu wo awọn akẹkọọ naa lati le ṣe ohun to yẹ lasiko.

O tẹsiwaju pe ara airi owo oṣu gba lasiko wa lara ohun ti o ko ba ọpọlọpọ awọn akẹkọọ naa tori awọn ọmọ olukọ naa wa lara wọn.

Aguda ni oun gbagbọ pe ti ile ẹkọ naa ba fi iṣẹlẹ ya awọn akẹkọọ naa, iru afojudi bayii ko ni sẹlẹ mọ.

Iya afin Oyewole Ronke ti o je olutaja ounjẹ ni agbegbe ile ẹkọ naa rawọ ẹbẹ si awọn adari Fasiti naa lati wo bi nnkan n lọ kaakiri orilẹ-ede Naijiria ki wọn fi gba awọn akẹkọọ naa laye lati ṣe iforusilẹ.

Nigba ti akọroyin BBC News Yoruba kan si Bode Olofinmuagun, ti o jẹ adari fun eto iroyin ile ẹkọ fasiti ipinlẹ Ekiti, o ni abajade ipade ti awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa ṣe ni wọn ti fi ranṣẹ si adari awọn akẹkọọ ti esi Lẹta naa si wa kaakiri.

O ni ile ẹkọ naa ko i tii yi ipinnu rẹ pada bayii.

Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ ko i tii si idahun si ibeere awọn akẹkọọ naa lati ọdọ awọn adari Fasiti ipinlẹ Ekiti ati ijọba ipinlẹ naa.