Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Published

Awọn ọdọ kan ti ṣe iwọde lawọn ilu nlanla ni Naijiria tako ipo to ọrọ aje Naijiria wa

Iwọde naa lo waye tako ikilọ ileeṣẹ ọlọpaa to ni kii ṣe akoko yii lo yẹ ki iwọde kankan waye

Lara awọn ibi ti wọn ti ṣe iwọde naa ni ilu Eko, Abuja, ipinlẹ Oyo ati Rivers

Ẹwẹ, ọlọpaa fi gaasi tajutaju tu awọn oluwọde ọhun ka ni Port Harcourt

______________________________________________________________

Eeyan marun un lo ti dero ile iwosan nilu Eko lẹyin ti gaasi kan bu gbamu nibẹ

Olori ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nibẹ, Margaret Adeseye, sọ pe

Silinda gaasi 25kg kan to n jo tẹlẹ ni ina ran mọ, ko to bu gbamu

______________________________________________________________

O le ni aadọta eeyan ti agbebọn ṣekupa lopin ọsẹ kaakiri iha ariwa Naijiria

Nipinlẹ Plateau, ko din ni aadọta eeyan ti awọn afurasi darandaran pa laarin ọsẹ kan

Ni Kebbi, awọn ọmọ ẹgbẹ agbesunmọmi Lakurawa ṣekupa fijilante mẹtala

Ni Katsina, wọn ji aadọta eeyan lọ nigba ti wọn ṣekupa eeyan mẹfa mii

A gbọ pe ọjọ Satide ni wọn bẹrẹ si n ṣọṣẹ titi di ọsan ọjọ Aiku