Kò ṣe é má gbọ̀ọ́
Kò ṣeé maá gbọ̀ ọ́
Hmmm, ariwo ń lọ lórí ayélujára pe wọn fẹẹ yọ olori ile igbimọ aṣofin agba, Godswill Akpabio, kuro nipo.
Bẹẹ ni, lanaa ni iroyin naa gbode kan, tí wọn sì ni DSS kun inu ọgba ile igbimọ asofin naa.
Àmọ́ olugbaninimọran fún aare lórí ọrọ ile aṣofin, Ṣenetọ Bashir Garba, ti ṣàlàyé ohun tó fà ahesọ ọrọ yìí.
Mo wà lára àwọn tó du ẹ̀mí Bọbọ B ko ma baa ku, àmọ́ ó lọ sinmi ni.
Gbajumọ osere, Toyin Adegbọla tawọn eeyan mọ si Ajọkẹ aṣẹwo to re Meka lọ ń tara poro bẹẹ lórí ikú Ayobami Olabiyi, Bobo B.
Toyin Adegbola fikùn pé oṣu meji sẹyin ni àìsàn kan ti n ba Bobo B finra, ti ko si tete mọ.
Ṣo o ranti awọn ajijagbara Yoruba Nation to ya bo ofiisi ijọba ipinlẹ Oyo loṣu kẹrin ọdun yii?
Bẹẹ ni o, ki la tun ri gbọ nipa wọn?
Ọkan ninu wọn, Lateef Adejumo, ti ku sahamọ ijọba bayii.
Toò, ki lo waa ṣẹlẹ sawọn to ku?
Gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Yorùbá Nation mẹtadinlọgbọn yoku, tí ń fi ojú bá ilé ẹjọ́
