Kò ṣeé má gbọ̀ọ́

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Kò ṣeé má gbọ̀ọ́
Kò ṣeé má gbọ̀ọ́
Published

Ẹgbẹ́ àwọn tó ń ta nǹkan ọ̀sìn àti oúnjẹ lorílẹ̀ èdè Niger ti kọminú pé

O ṣeéṣe kí owó àwọn nǹkan ọ̀sìn tún gbẹ́nu sókè ṣáájú ọdún Iléyá tó ń bọ̀ lọ́nà

Wọ́n ní èyí yóò rí bẹ́ẹ̀ látàrí òfin tuntun tí ìjọba Niger ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé kalẹ̀ pé

Wọ́n kò gbọdọ̀ kó nǹkan ọ̀sìn jáde kúrò lorílẹ̀èdè náà mọ́

Lọ soju opo BBC Yoruba lati mọ eredi igbesẹ naa

________________________________________________________________

Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Wilfred Afolabi ti sọ pe

Ida aadọrun awọn ajinigbe ti ọwọ ọlopaa n tẹ nipinlẹ naa lo wa lati ariwa Naijiria

Afolabi lo sọ ọrọ yii ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ igbohuna ipinlẹ ọhun

_______________________________________________________________

Ni ipinlẹ Kogi

Awọn ajinigbe ti ṣekupa eeyan mẹta lẹyin ti wọn ji ori kan gbe nijọba ibilẹ iwọ oorun Yagba

Ọsẹ to kọja ni wọn ji Pa Dada James Ogunyanda gbe, ti wọn si bere ọgọrun miliọnu naira gẹgẹ bii owo itusilẹ rẹ

Iroyin ni asiko ti awọn eeyan ori ade naa n wa owo irusilẹ rẹ lawọn ajinigbe naa tun ṣọṣẹ, ti wọn si gbẹmi eeyan mẹta mii