You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Pásítọ̀, Lèmọ́mù àti olórìṣà ń lo omi láti dájọ́, kí ló dé tí ẹ̀ ń dá Osun lẹ́jọ́?
Yoruba ni ibi gbogbo la ti n ko adiẹ, akoko lo kan yatọ.
Bi wọn ti n se ọdun Osun nilu Osogbo wa ni orilẹede Naijiria pẹlu ayẹyẹ alarinrin naa ni wọn n se ọdun naa nilu Itakò, lorilẹede olominira Benin.
Akọroyin BBC Yoruba to wa nibi ayẹyẹ Odun Osun nilu Itakò tọdun 2023 jabọ pe ẹsẹ ko gbero lasiko ọdun naa.
Koda, ọpọ agan to n woju Ọlọrun ni wọn tọrọ ọmọ fun, tawọn olujọsin orisa Ọsun si wọ asọ funfun lati sami ọdun naa.
Koda, arugba Osun gan wa nibi ayẹyẹ yii, to si gbe igba sori, eyi to sọkalẹ lojubọ odo Osun nilu naa.
Tó bá ku ọjọ́ méje, Ìyá Ọsun kò ní jẹ ata tàbí epo, èsò àti kókó nìkan ni oúnjẹ rẹ̀ - Iya Osun
BBC Yoruba wa finmu-finlẹ nipa bi wọn se n bọ Osun Osogbo nilu Itakò.
Nigba to n dahun ibeere yii, Iya Osun salaye pe ipalẹmọ fun ọdun naa yoo bẹrẹ nigba to ba ku ọjọ meje.
O ni akoko yii ni iya ọsun ko ti ni jẹ ounjẹ to ni iyọ, ata tabi epo ninu amọ kikida eso ati koko nikan ni yoo maa mu.
Bakan naa lo ni ẹni ti yoo ba jẹ Arugba lọdun naa gbọdọ ti de sọdọ iya Osun nigba to ba ku ọjọ meje.
"Tó bá ku ọjọ́ méje, Ìyá Ọsun kò ní jẹ ata tàbí epo, èsò àti kókó nìkan ni oúnjẹ rẹ̀.
Arugba naa si ti gbọdọ de ọdọ mi fun akoso to ba yẹ fun ọdun naa.
Ẹni ti ko mọ ọkunrin ri ni a maa n fi se Arugba, ti o si gbọdọ wa lai ni abawọn."
Bakan naa, Iya Osun tun mẹnuba awọn eroja ti wọn fi n bọ Ọsun ati eroja to wa ninu igba ti wọn n gbe lọ si ojubọ Osun nim ọdọọdun.
Lara awọn eroja naa ni "Bisikíìtì, súùtì, ọtí ẹlẹ́rìndòdò, oyin ìgàn, ẹran àgbò funfun ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Bakan naa lo ni orogun, igbakọ, eso, ọlọ ata ati bẹẹ bẹẹ lọ maa n wa ninu igba ti Arugba maa n ru lọ si ojubọ Osun.
Pásítọ̀, Lèmọ́mù àti olórìṣà ń lo omi láti dájọ́, kí ló dé tí ẹ̀ ń dá Osun lẹ́jọ́?
Nigba to n sọ pataki omi fun bibọ Osun ati fun gbogbo eeyan, Mama Osun ni omi se pataki nitori Pasitọ, Lemọmu ati awọn olorisa yoku lo maa n lo omi, eyi to jẹ idamọ Osun.
O wa n fi apa janu pe ki lo de ti awọn eeyan fi maa n koro oju si Osun tabi da a lẹjọ.
Yeye Osun ni Osun jẹ orisa to fẹ imọtoto, ti awọn to maa n bọ si gbọdọ jẹ ẹni mimọ.
O fikun pe awọn ọmọ omi maa n ni oju aanu pupọ amọ wọn buru pupọ nitori wọn korira iwa igberaga tabi afojudi si wọn.