Ẹ̀dínwó epo bẹntiróòlù tuntun: Tani yóò san án? Tani yóò jẹ anfani rẹ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Kò jẹ tuntun pé ìjọba Aare Bola Tinubu tí kéde ẹ̀dínwó lórí epo bentiroolu tí àwọn ọlọ̀kọ nlo fún Osu kan ṣùgbọ́n òpó ìbéèrè tí àwọn èèyàn ń béèrè lórí rẹ ni a dáhùn nínú ìròyìn yii
Bí àwọn miran ṣe ń binu pé aadota náírà péré ni anfani tí wọn yóò jẹ ní agbègbè tí wọn ní àwọn ọmọ Naijiria miran ni pé tí wọn to ọgọ́rùn un náírà lórí lita epo kan
Àwọn miran ń sọ pé ṣe 'subsidy' tí àárẹ̀ Tinubu yọ tẹ́lẹ̀ lo fi ọgbọ́n dá padà tàbí bẹẹ kọ
Sugbon Taiwo Oyedele to ṣe ìkéde ẹ̀dínwó máa tí sọ pé ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ rara
Àwọn miran si n sọ pé ó dàbí pé ìjọba Tinubu ṣẹ̀ṣẹ̀ ń fura pé orí ń tà ara ilu ni
Taiwo Oyedele ṣàlàyé pé gbogbo onimọto pàápàá àwọn ọlọkọ èrò ni yóò jẹ anfani náà nitoripe ẹbí, ara ati ojulumo ni ó ń wọ ọkọ̀ èrò káàkiri Nàìjíríà
Àwọn miran si n sọ pé ó fé dabi pé ọwọ́ Abu ni a fi ń ṣe Abu ni àlejò ni ọ̀rọ̀ ohun jọ
Ṣé lóòótọ́ ni owó epo ti di ₦1900?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lowurọ ọjọ Abamẹta lawọn ọmọ Naijiria ji si iroyin kan to lọ kaakiri pe owo ori epo bẹntiroolu ti di ẹgbẹrun meji o din ọgọrun kan naira (N1,900).
Iroyin to jade lawọn iwe iroyin abẹle kan lorilẹede Naijiria lowurọoni n sọ wi pe o ṣeeṣe ki awọn ile epo kan bẹrẹ si ni ta bẹntiroolu ni ẹgbẹrun meji o din ọgọrun Naira ni Eko, PortHarcourt, Warri, ati Calabar.
Ki ni iwadii BBC fihan lawọn ipinlẹ kan?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iwadii ileeṣẹ BBC News Yoruba kaakiri awọn ipinlẹ bii Eko, Ogun, Ọṣun ati Kwara fihan pe ko si ohun to jọ bẹẹ.
Ni ipinlẹ Ogun laarin ọdunrunleẹgbẹrun kan ati marun naira (1, 355) si ẹgbẹrun kan ati ọọdunrun o le mejidinlọgọrin naira ni wọn n ta epo lọ ile epo ti a de.
Ni ipinlẹ Ọṣun ile epo NNPC to wa lagbegbe Abeere ni ilu Osogbo n ta epo naa ni ẹgbẹrun kan o le ọọdunrun ati mejilelogun Naira (N1322) bi o tilẹ je pe oju itepo kan ninu oju itepo ogun to wa nile itepo naa ni wọn ti n ta epo.
Ni ilu Eko kaakiri awọn agbegbe ile epo laarin ẹgbẹrun kan o le ọọdunrun ati ọgọta Naira si ẹgbẹrun kan o le ọọdunrun ati aadọ̀rin Naira ni wọn n ta epo.
Iwadii akọroyin wa kan fidi rẹ mulẹ pe awọn oṣiṣẹ ileepo kan ti oun ba sọrọ sọ wi pe awọn pẹlu n gbọ awuyewuye pe owo epo fẹ lọ soke ṣugbọn awọn ko tii gbọ nnkankan lati ọdọ awọn ọga awọn.
'A ko tii maa ri epo to wa silẹ ra'
Pupọ awọn onimọto ati awakọ ero ti a ba sọrọ ṣalaye pe awọn ko tii maa ri ọwọ adinku naa. Wọn ni o jẹ ohun ti ko dara pe nigba ti ijọba ba kede ẹkunwo epo, kiakia lawọn ontaja epo maa n tẹle aṣẹ naa, amọ to ba ti di pe ki wọn din owo epo ku ni wọn maa n fi ẹsẹ falẹ


























