Kò ṣeé má gbọ̀ọ́

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Kò ṣeé má gbọ̀ọ́
Kò ṣeé má gbọ̀ọ́
Published

Ẹgbẹ awọn agbẹjọro ni Naijiria, NBA ti kede pe

Ko tọna, bẹẹ ko ni ba ofin mu bi Aarẹ Bola Tinubu ṣe kede ilu o fararọ nipinlẹ Rivers, ati bo ṣe da gomina Siminalayi Fubara duro

NBA ni gẹgẹ bii alakale ofin, ohun to n ṣelẹ ni Rivers ko tii buru to ki Aarẹ kede ilu o fara rọ nibẹ

__________________________________

Ipinlẹ Rivers naa ni ṣi wa

Gomina Fubara ti rọ awọn eeyan ipinlẹ ọhun gba alaafia laaye ki wọn ma si ṣẹ si ofin lasiko yii

Fubara lo sọ ọrọ naa ninu atejade kan to fi lede lẹyin ikede Aarẹ to ni ko lọ rọọkun nile fun oṣu mẹfa gbako

Lọ soju opo BBC Yoruba fun ẹkunrẹrẹ

_________________________________

Nipinlẹ Ondo

Awọn eeyan ilu Ala, nijọba ibilẹ Guusu Akure ti sẹ ifẹhonuhan lọ si ọọfiisi gomina Lucky Aiyedatiwa

Latari bi awọn afurasi darandaran ṣe gbẹmi awọn eeyan kan nibẹ laipẹ yii

Ṣaaju ni iroyin ti kọkọ sọ pe awọn darandaran naa kọlu abule mẹrin nipinlẹ Ondo, ti wọn si gbẹmi agbẹ to le ni ogun