Kò ṣeé má gbọ̀ọ́

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Kò ṣeé má gbọ̀ọ́
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti sọ pe oju ọna one-way ni ọkunrin ti wọn ṣeṣi yinbọn pa ọmọ rẹ niluu Ibadan lana gba ṣaaju iṣẹlẹ ọhun

Agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Adewale Osifeso sọ pe taya ọkọ ọkunrin naa lawọn fẹ yinbọn si ko to ba ọmọ rẹ, Kehinde Alade

Lọ soju opo BBC Yoruba fun ẹkunrẹrẹ

__________

Nipinlẹ Osun

Ko din ni ẹlẹwọn mẹfa to salọ kuro lọgba ẹwọn ilu Ilesha lẹyin ti ojo nla kan rọ loru ọjọ Iṣẹgun

Agbẹnusọ ọgba ẹwọn naa, Umar Abubakar ni, awọn ti bẹrẹ iṣẹ lorii bi wọn yoo ṣe ri awọn ẹlẹwọn naa mu pada laipẹ

_________

Ọkunrin kan ti dana sun iyawo ati ọmọ rẹ nijọba ibilẹ Osisioma Ngwa, nìpínlẹ̀ Abia

Awọn ti ọro naa ṣoju wọn ni òru tí gbogbo èèyàn ti sùn ni ọkùnrin náà da epo bẹntiróòlù sílé wọn, tó sì dáná si pẹlu iyawo ati ọmọ rẹ ninu ile

Ẹsun to fi kan iyawo rẹ ni pe o doju ti oun lasiko to wa bere owo ounjẹ lọwọ oun ninu ọja

Fun ẹkurẹrẹ