Omar ọmọ ọdún mẹ́tàlá láti Gaza pàdánù òbí rẹ̀ méjèèjì nínú ìkọlù Israel
Omar ọmọ ọdun mẹtala lati Gaza ṣadeedee di ọmọ orukan lẹyin to padanu baba ati ìyá rẹ ninu ikọlu Israel.
Omar ni "orukọ baba mi ni Ahmad Muhammed Lubbad.
Abẹ okuta yii lo ti jade laye.
Iya mi wa ni ẹgbẹ rẹ, pẹlu aburo mi obinrin.
Bo tilẹ jẹ pe aarin wọn lo wa, ohunkohun ko ṣẹlẹ si i."
Ni bayii, Omar ati aburo rẹ ti di ọmọ orukan.
Omar gbẹ ilẹ lati doola ẹmi awọn obi rẹ, ṣugbọn ẹpa o boro mọ.
O ni iya oun jẹ eeyan to n mu nnkan rẹwa, ayaworan ni nigba ayé rẹ.
Omar ni awọn maa jọ n lọ pọn omi ti inu wọn si maa n dun papọ.
Awọn ọmọde yii tun padanu iya-iya wọn ati awọn ẹgbọn baba wọn.
Ẹgbọn baba wọn ọkunrin lo n tọjú wọn bayii.
Oun naa ko nile lori.
Omar ni oun n da wa, oun si n ṣafẹri awọn obi oun.
"O wu mi ko jẹ pe wọn si wa laaye k'a si di mọlebi pada.
Ṣugbọn o ti parí, a ti tuka," Omar ṣalaye pẹlu ẹdun ọkan.






