Kò ṣeé má gbọ̀ọ́
*Ile-ẹjọ giga ilu Ibadan ti da gbogbo ẹsun ti wọn fi kan Olori Ooni tẹlẹ Naomi Silẹkunọla, ati Oriyọmi Hamzat, nu*
Bakan naa ni kootu wọgile ẹjọ ti ọga ile ẹkọ Islamic High School to wa ni Bashorun; Fasasi Abdulahi naa n jẹ pẹlu
*Awọn eeyan naa lo wọ gau lẹyin iku ọmọde marundinlogoji to fẹ gba ounjẹ ọdun ti olori Naomi pese loṣu Kejila ọdun to kọja*
_____________________________________________________________________
Ijọba apapọ ti sọ pe ko buru bi Aarẹ Bola Tinubu ṣe kede ilu o fararọ ni nipinlẹ Rivers,
*Adajọ agba Naijiria, Lateef Fagbemi ni igbesẹ naa waye ki ipinlẹ ọhun ma ba a daru*
Fagbemi lo sọ ọrọ naa lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Abuja
*Ẹkunrẹrẹ ohun to sọ wa loju opo BBC Yoruba*
___________________________________________________________________
Ni Kwara
*Igbẹjọ Abdurahman Bello, aafaa to ṣekupa ọrẹbinrin rẹ, Afsot Yetunde to si kun wẹlẹwẹlẹ niluu Ilorin tẹsiwaju lonii*
Agbẹjọro mọlẹbi oloogbe sọ fun BBC pe afunrasi naa ti kuro ni ahamọ ọlọpaa bayii, o ti wa lọdọ ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS
*Fun ẹkunrẹrẹ*