Mo gbọ́ pé àwọn kan láwọn fẹ́ jíbò l'Osun, eré ọmọdé ni, ìbò Osun ò ṣe é fọwọ́ kàn – Gómìnà Adeleke

Gomina Ademola Adeleke. O n mu ẹrọ gbohungbohun dani bo ṣe n sọrọ, o de fila alawọ ofeefe, o si wọṣọ alawọ aró

Oríṣun àwòrán, Gov. Ademola Adeleke/Facebook

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Ọrọ to ba dani loju ki i kọsẹ lete ni Gomina ipinlẹ Osun;Ademola Adeleke, fi ọrọ rẹ ṣe lọjọ Aje ana, nigba to sọ nita gbangba pe ko si kinni kan ti yoo ṣe ibo gomina ti yoo waye nipinlẹ Osun lọjọ kẹẹẹdogun oṣu Kẹjọ ọdun 2026.

Oke Ila ni Gomina Adeleke ti sọrọ naa, nijọba ibilẹ Ifedayo, ipinlẹ Osun, lasiko iwọde ipolongo ibo to ku si dẹdẹ naa.

Adeleke sọ pe ibo yii ko ṣee ṣe magomago si, bẹẹ ni ko ṣee ji pẹlu.

O ni ibo awọn eeyan Osun ni yoo sọ ẹni to jawe olubori, ko si sohun ti yoo ṣe ibo naa bi wọn ba ṣe di i.

"Mo gbọ pe awọn oloṣelu kan ti n leri lati ji ibo, nibo ati bawo?"

Gomina Adeleke to sọrọ pẹlu idaniloju, tun beere ibeere ti ko reti esi fun, o ni:

"Mo gbọ pe awọn oloṣelu kan n leri lati ji awọn ibo lọ. Nibo ati bawo ni wọn ṣe fẹẹ ṣe e?

" Ibo Osun ko ṣee fọwọ kan o. Ipinlẹ Osun leyi, ọkan orilẹede Yoruba. Ko sẹni to le ṣe èrú fun wa nibi."

Gomina fi kun ọrọ rẹ pe awọn eeyan ipinlẹ Osun ti ṣetan lati da aabo bo ibo ti wọn ba di.

O ni ikọlu ati ahesọ tawọn alatako n gbe kiri wulẹ n fi ifẹ oun si ọkan araalu si I ni.

Adeleke ko ṣai rọ awọn eeyan Osun lati ma ṣe bẹru rara, o ni idibo yoo waye, oun yoo si jawe olubori.

O rọ wọn lati ma ṣe ta ibo tabi kaadi idibo won, ki wọn si foju ṣọri lọjọ idibo, ki wọn duro ti ibo ti I ṣe agbara wọn.

Wo èèyàn márùn-ún tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Osun ń wá látàrí rògbòdìyàn òṣèlú

Ọkọ ti gilaasi rẹ fọ lasiko rogbodiyan l'Osun pẹlu ẹyin ẹnikan ti wọn le plasta mọ latari bo ṣe farapa ninu rogbodiyan naa.

Oríṣun àwòrán, Screebn shot/Photo collage

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti kede pe oun n wa awọn eeyan marun-un kan ti wọn furasi pe wọn lọwọ ninu rogbodiyan oṣelu to n waye kiri nipinlẹ naa.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Osun, Abiodun Ojelabi, fi sita ni wọn ti ṣalaye pe akọtun iṣẹ ti n lọ lati mu awọn eeyan ti wọn furasi pe wọn lọwọ ninu rogbodiyan to mu ẹmi awọn eeyan kan lọ, to si tun ba dukia jẹ nipinlẹ Osun.

Tẹ o ba gbagbe, lati bii oṣu kan sẹyin ni nnkan o ti i fararọ lagbo oṣelu nipinlẹ naa, pẹlu bi ọjọ idibo sipo gomina ṣe n sunmọle.

Bawọn oloṣelu ṣe n naka aleebu sira wọn lori rogbodiyan naa ni awọn igun awakọ ero naa n ba ara wọn fa a.

Eyi ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa sọ pe o n da omi alaafia ilu ru.

Wọnyi lawọn eeyan ti ileeṣẹ ọlọpaa Osun n wa

  • Dauda Olamilekan, ẹni tawọn eeyan mọ si Emir.
  • Taoreed, ti inagijẹ rẹ n jẹ 'Small Rugged.
  • Adetunji Kamoru Olatunde.
  • Saka Afees, ti inagijẹ rẹ n jẹ 'Terror'
  • Adeyemi Saheed.

Kọmandi ọlọpaa Osun wa rọ awọn araalu to ba le ṣeranwọ, pẹlu tita wọn lolobo nipa ibi tawọn eeyan wọnyi wa lati tete ṣe bẹẹ.

Bakan naa ni wọn rọ wọn lati tẹsiwaju ninu ifisun nipa awọn eeyan ti wọn ba n lọwọ ninu iwa ọdaran lagbegbe wọn.

Awọn to ti ba rogbodiyan oṣelu lọ si ọrun ojiji l'Osun

Lara awọn eeyan ti iroyin fi lede pe wọn padanu ẹmi ninu awọn rogbodiyan to waye nipinlẹ Osun laipẹ yii ni:

Ọdọmọkunrin kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Olapade Ezekiel.

Ọmọ naa ṣe kongẹ ikọlu iku ni ilu Ilobu.

*Kọmureedi Abdullateef Olamilekan.

*Kazeem Akande; ẹni aadọrin ọdun (70) ti wọn pa niluu Osogbo

*Ajayi Aderogba niluu Esa-Oke ati ẹnikan ti wọn pe orukọ rẹ ni Eluyera, niluu Ikire.

Fàákája láàrin ọlọ́pàá àti iléeṣẹ́ ọmogun oju-omi l'Osun lórí àwọn jàndùkú tó fẹ́ gba gáréèjì, àwọn tọ́ọ̀gì tún jí káàdì ìdìbò kó lọ

Ọga ọlọpaa Tunji Disu wọ aṣọ 
ọlọpaa pẹlu fila, Gomina Ademola Adeleke wọ aṣọ olomi buluu pẹlu awo loju rẹ

Oríṣun àwòrán, Gov Ademola Adeleke

Rogbodiyan to n ṣẹlẹ nipinlẹ Osun ṣaaju eto idibo gomina to n bọ si n tẹsiwaju lẹyin ti a gbọ pe awọn jabduku yawọ wọọdu INEC to wa nile ẹkọ Oyinlola DC School ni Okuku nibi ti wọn ji kaadi idibo ti ajọ naa n pin atawọn nnkan mii lọ.

Iṣẹlẹ yii ni a gbọ pe o ṣakoba fawọn osiṣẹ INEC ti wọn pin kaadi idibo tori onikaluku fẹsẹ fẹ lẹyin tawọn janduku ọhun de.

Olugbe ilu Okuku kan, Gbadebo, sọ fawọn akọroyin pe ṣadeede lawọn janduku naa ya wọ ile ẹkọ ti INEC ti n pin kaadi idibo naa.

Gbadebọ ni awọn janduku ọhun yinbọ soke bi wọn ti ji awọn kaadi idibo to wa lori aga ko lọ.

Olugbe ilu Okuku naa sọ pe awọn janduku ọhun to mẹjọ ti ya wọ ile ẹkọ ti ajọ INEC ti n pin kaadi idibo.

Ẹwẹ, agbenusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, Abiodun Ojelabi, sọ pe Kọmiṣọna ọlọpaa Ibrahim Gotan ti bẹnu ẹtẹ lu iṣẹlẹ naa.

Ojelabi fikun ọrọ rẹ pe kọmisọna ọlọpaa ti paṣẹ iwadii kikun lori iṣẹlẹ ọhun, ati pe o fẹ kawọn to wa nidii naa oju wina ofin.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa tun fi dawọn araalu loju wi pe awọn ọlọpaa ko ni kaarẹ lati maa tẹle ofin bi wọn ṣe n ṣiṣẹ wọn.

Bakan naa ni o rọ awọn araalu lati ma fọwọ pada ofin loju.

Ọlọpaa ṣekọlu sawọn ọmogun oju omi lati tu Asiri Eniba atawọn mii silẹ - Ijọba Osun

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Osun ti fẹsun kan ileeṣẹ ọlọpaa wi pe wọn ṣe ikọlu si ọmogun oju-omi kan niluu Ile-Ife lana ọjọ Aiku ọjọ kẹrindinloọgbọn oṣu Keje yii lati tu Kazeem Oyewale tawọn eeyan mọ si Asiri Eniba silẹ.

Ijọba ipinlẹ Osun ṣapejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bi eyi to lewu fun eto aabo ipinlẹ naa, nigba ti o kepe Aarẹ Bola Tinubu ati oludamọran aarẹ lori eto aabo, Nuhu Ribadu lati dasi ọrọ naa.

Iṣẹlẹ yii waye lẹyin wakati diẹ tawọn janduku kan fẹ fipa gba ibudokọ kan lagbegbe Mayfair niluu Ile-Ife nibi tawọn ti fẹsẹ fẹ nigba ti ibọn n dun lakọ lakọ.

Ohun ti a gbọ ni pe awọn ologun ko gba fawọn janduku naa lati ri ibudokọ naa gba.

Ninu ọrọ rẹ, kọmiṣọna fun eto iroyin ati ilanilọyẹ nipinle Osun, Kolapo Alimi, so pe awọn ọlọpaa tẹle Eniba atawọn janduku ti wọn fẹ gba ibudokọ naa.

Ariwo awọn eeyan ilu Ile-Ife ni a gbọ pe ileeṣẹ ọmogun oju omi gbọ ti wọn fi fọwọ ofin mu awọn janduku marun un naa.

Ijọba tun fẹsun kan komiṣọna pe oun lo pe ileeṣẹ ọmogun oju-omi lori foonu lati tu awọn janduku naa silẹ, amọ, ileeṣẹ ọmogun oju omi sọ pe ayafi ti aṣẹ ba wa lati oke lawọn le tu wọn silẹ.

Lẹyin naa nijọba ipinlẹ Osun sọ pe kọmiṣọna ọlọpaa fi ọkọ mẹrin ko awọn ọlọpaa lati lọ ṣekọlu si ọmogun oju-omi kan.

A gbọ pe awọn ọlọpaa naa yin tajutaju sawọn ọmogun oju omi naa lati fipa tu awọn janduku ọhun silẹ.

Bakan naa ni a tun gbọ pe awọn ọlọpaa ko gba ibọn to wa lọwọ awọn janduku naa nigba ti awọn ọmogun oju omi fọwọ ofin mu wọn.

Iṣẹlẹ yii lo tun jẹ tuntun ninu rogbodiyan to n waye nipinlẹ Osun ṣaaju eo idibo gomina ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹjọ to n bọ.