You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
'Epo ni Mummy ní kí n wá gba, àfi tó da omi gbígbóná lé mi lára pé mò ń fẹ́ ọkọ òun'
Iroyin Kayefi lo jẹ pe iru nnkan bayii ṣi n ṣẹlẹ laarin awọn obinrin.
BBC Yoruba ba arabinrin Endurance Peter sọrọ, ẹni to n jẹ irora nile iwosan lọwọ lọwọ koda ti ko le wọ aṣọ latari irora omi gbigbona to ti sọ ara rẹ di bibo.
Endurance kii ṣe ajoji si obinrin to ṣe aburu yii sii koda o ṣalaye pe arabinrin naa pe oun lati wa gba Epo ni ile wọn ni toun si lọ sibẹ.
"Mummy pe mi ki n wa gba epo ti mo ba ọkọ oun ṣe. O gbe ijoko pe ki n jokoo... o oun gbọ pe emi n fẹ ọkọ oun, mo dẹ bọ bata silẹ pe mi o fẹ ọkọ rẹ o".
Endurance ṣalaye pe arabinrin naa ko gba oun gbọ to si bẹrẹ si ni di ọrọ naa le oun lori afi ti obinrin naa lọ gbe omi gbigbona to si da a si i lara.
O ni ko duro sibẹ, ṣe lo tun bẹrẹ si ni lu oun titi di igba ti eeyan kan to wa ni tosi wa doola oun to si gbe e lọ si ile iwosan.
Ki ni ọkọ awọn mejeji sọ?
Endurance ni ọkọ arabinrin naa n bẹ oun pe oun ko mọ nnkankan nipa aburu ti iyawo rẹ ṣe to si sọ fun awọn nọọsi pe ki wọn tọju Endurance daadaa wipe oun yoo san gbogbo owo itọju.
Bakan naa, BBC Yoruba ba ọmọ Endurance sọrọ. Godwin ṣalaye pe bi oun ba ni ki oun lọ si agọ ọlọpaa nibi ti obinrin naa wa, oun le ṣi iwa hu.
"O tẹ mi lọrun ki n joko ti iyawo mi ni ileewosan lati boju to itọju rẹ.
Lọkan temi, mo ṣetan lati fi gbogbo nnkan silẹ fun Ọlọrun ṣugbọn awọn eeyan lo gba imọran pe ka ṣe ẹjọ tori pe bi obinrin naa ba ri aye ni, o ṣeeṣe ko pa iyawo mi."