Àṣà ìdárayá kan réè tàwọn olùdíje ti ń jẹ́ ìgbájú olóyì ní pápá ìṣiré
Maja masa laa mọ akikanju.
Bi eeyan ko ba to gbangba sun lọyẹ ko ma ba wọn kopa ninu ere idaraya yi taa mọ si Slap Kabaddi.
Lagbegbe Punjab, ni orileede Pakistan lawọn gende ọkunrin ti maa n dan ara wọn wo nipasẹ ẹni to ba le farada igbaju oloyi julọ.
O ṣe yin ni kayeefi pe igbati ni wọn fi n dan ara wo abi?
Bo ṣe ri si awa naa ni yẹn ṣugbọn lọdọ awọn to dagba sinu ere idaraya yi, ko jẹ tuntun.
Wọn a tun maa pe Slap Kabaddi ni "Thappap Kabaddi."
Ni agbegbe South Asia bi ijakadi ti ṣe gbalẹ lọdọ wa nibi ni ere idaraya yi naa ṣe gbajumọ.
O fẹ fara pẹ ijakadi ṣugbọn kaka ki awọn oludije maa yi ara wọn mọlẹ, igbaju ni wọn maa n da bo ara wọn titi ti eeyan kan yoo fi ṣubu tabi sọ pe oun ko ṣe mọ.
Ninu ere idaraya yi awọn oludije mejeeji gbọdọ doju ija igbati kọ ara wọn.
Haji Tassawur jẹ ọkan lara awọn ogbontarigi ere idaraya yi ni Punjab Pakistan.
O ni oludije a maa gba ami nipa dida igbati bo alatako rẹ.
''Ẹni keji naa a si maa pa ami ayo yẹn rẹ nipa fifi ọwọ di igbati yi''
Ninu alaye rẹ, gbigba eeyan lẹṣẹ dipo igbaju ko bo ofin ere naa mu.
Eeyan to ba ṣe bẹẹ yoo padanu ami ayo ni gẹgẹ bi o ṣe ṣalaye.
Ko si gbedeke lori iye igba to le fọ alatako rẹ leti.

Ero to n wo ere Kabaddi n pọ si ni
Tassawur tẹsiwaju ninu alaye rẹ pe awọn eeyan fẹran lati maa wa wo ere Slap Kabaddi dipo ere idaraya ijakadi tawọn mi a maa ṣe.
O ni awọn to ba jaweolubori ninu ere idaraya yi a maa gba ọpọ ẹbun owo ati ife to ṣafihan pe wọn bori ninu idije naa.
Lọdọ awọn oludije bii Haji bibori kii ṣe ohun to ṣe pataki julọ.
O ni ''bi mo ba wa lori papa iṣere mo maa n ronu nipa Ọlọrun.Mo si tun maa n gbiyanju lati daabo bo ara mitabi ki n farapa.Ko si ere ninu kiemi tabi alatako mi farapa.Ero mi ni bi mo ṣe maa bori ti wọn o si ni ṣemi leṣe ninu idije naa''






