Hisham Wadan: Ìlanilọ́yẹ̀ nípa àrùn ojú ló mú mi ṣe fíìmù Lost in London
Asamọ kan lo ni agbara n bẹ ninu aidape ara, bẹẹ si ni agbara lati se ohunkohun wa ninu akande ẹda kọọkan.
Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu Hisham Wadan, tii se ọmọ ọdun mejila ti oju rẹ n fọ lọ diẹdiẹ amọ to pinnu lati jẹ eeyan laye lai fi ti ipenija naa se.
Ọmọdekunrin naa ni oun ni ipenija bakan naa nipa iriran ni alẹ, eyi to pe ni Night Blindness.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Nigba to n ba BBC sọrọ, Wadan salaye pe ọpọ eeyan lo maa n fi iwọsi lọ nitori aisan oju to ni, ti wọn si maa n fi se yẹyẹ ni ọpọ igba.
Eyi si lo mu ki ọmọdekunrin naa se fiimu kan nipa awọn iriri to n la kọja to fi mọ idojukọ to n koju lati ọdọ awọn akẹẹgbẹ rẹ.
Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìtàn ayé Henry Fajemirokun, olówó tó fi owó mọ Olúwa àti ènìyàn
- Ìtàn ayé Taiwo Oredein rèé, àgbà òṣèlú tó parí ayé rẹ̀ sọ́gbà ẹ̀wọ̀n
- Wo ìgbẹ̀yìn àwọn ọlọ̀tẹ̀ Yorùbá tó ran Fulani lọ́wọ́ láti kógun ja ìlú Osogbo
- Ìtàn ìgbé ayé Bode Thomas rèé, ó kọ́ wa láti máa kó ẹnu wa ní ìjánu
- Ṣo mọ̀ pé J.F Odunjo jẹ aṣòfin àti mínísítà nílẹ̀ yìí, yàtọ̀ sí pé ó jẹ́ òǹkọ̀wé?
- Ìtàn Àrọ̀gìdìgbà jẹ́ kí ń rò pé bàbá mi yan Yemọ̀ja ní àlè - Ọmọ Fagunwa
- Ó pé ọdún mẹ́rìnlélàádọ̀ta tí Akintola kú, ìdí abájọ ìja rẹ̀ pẹ̀lú Awolowo rè é
- Ìtàn Gbọnka àti Timi, akọni méjì tó borí Aláàfin Ṣango
Wadam wa korajọ pọ pẹlu ibatan rẹ tii se ọmọ ọdun mejila bakan naa lati se fiimu kan to pe akọle rẹ ni ‘Lost in London.
Afojusun ọdọmọde naa to n gbero lati di gbajumọ osere lọjọ ọla, to fi se fiimu naa ni lati se itaniji ati ilanilọyẹ nipa awọn ọdọ to n ni ipenija oju.



