Africa in Pic: Àwọn àwòrán tó gbajúmọ̀ ní Afirika

Published

Ni bayii ti opin ọsẹ wọle de, ẹ jẹ ka jọ fun oju ni ounjẹ lati ipasẹ awọn aworan isẹlẹ manigbagbe to waye nilẹ Afirika laarin ọsẹ to n pari.

Awọn agbabọọlu meji ti wọn n fi ori du bọọlu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ori kan bọ́dì ree o. Philomeno Philemon Otieno, ọmọ ilẹ Kenya, gbe ori yọ ju Sadio Mane tilẹ Senegal lọ̀ ninu idijeAFCON, amọ Senegal papa fi ayo mẹta tẹ́ ori Kenya naa ba ni.
Ọmọkunrin kan to ko ẹ́ja lọwọ ni eti okun ilẹ South Afrika

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Bó ṣe wa ni liki, naa lo wa ni gbanja. Ọmọde yii lo ri ẹja Sadini gba nibi ajọdun ọlọdọọdun tawọn ẹja ti maa n sere wa si eti okun ni South Afrika
Ọpọ eeyan to n ko ẹja leti okun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ayẹyẹ nla ree o, eyi ko wa pọ ju. Ẹja ree lọfẹ-lofo yii, haa, ẹran ku si ilu ailọbẹ. ajọdun to n waye ni Durban ni ogunlọgọ ero maa n peju si lati ko ọpọ ẹja sadini
Ọlọpa mu awọn oluwọde kan

Oríṣun àwòrán, Ahmad Gharabli

Àkọlé àwòrán, Lọjọ Aje, awọn ọlọpa gba awọn eeyan to n se iwọde mu nilu Tel Aviv nitori iwa ẹlẹyamẹya lẹyin ti ọlọpa kan ti ko si lẹnu isẹ pa ọmọ ilẹ Ethiopia kan.
Awọn eeyan to n fi ẹhonu han

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Lọjọ Aiku, awọn alatilẹyin ẹgbẹ alatako nilẹ Congo ni wọn mu igbe bọnu lọjọ ajọdun ominira to waye lolu ilu Congo, Kinshasa
Ọgọọrọ awọn oluwọde loju tiit ni Sudan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Iwọde oselu miran lo tun n waye yii ni Omdurman, lorilẹede Sudan, ti oluwọde kan si n kesiawọn ologun lati fi ori apere silẹ
Awọn eeyan to n fi ẹhonu han

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Iwọde yii kọja bẹẹ. Omilẹgbẹ awọn eeyan ree, ti wọn n sewọde ni Sudan, koda, se ni ilu kun fọfọ
Awọn agbẹ to n sewọde ni China

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn agbẹ ọlọgbin owu ree nilu Lesotho tawọn naa n sewọde tako awọn olokoowo China tori owo ọja wọn ti ko tẹ wọn lọwọ
Agọ awọn atipo to ku ni Libya

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Agọ awọn atipo ree ni Libya, eyi ti ado oloro klu to si pa eeyan mẹrinlelogoji. Bi eeyan jẹ ori ahun, yoo sunkun lọ
Awọn ọlọpa to gbe oku

Oríṣun àwòrán, Empics

Àkọlé àwòrán, Bi ọdẹ ba ku, ọdẹ lo n soro lẹyin ọdẹ. Awọn ọlọpa kan ree ni Tunisia, ti wọn n gbe oku akẹẹgbẹ wọn ti ado oloro pa lasiko ti wọn n paraaro yika ilu lọ̀ọjọ Ẹti lọ si iboji.
Awọn panapana n pa ina , ti ọpọ mọto si jona di eeru
Àkọlé àwòrán, Ẹmi sofo ,ọkọ ati sọọbu tun jona nilu Eko lorilẹede Naijiria lasiko ti ina bu gbamu ni aarọ Ọjọbọ ladugbo Ijegun nibiti ọpa epo rọbi wa.