Kola Ologbondiyan: PDP ni yóò mú ọmọ Nàíjíríà kúrò lóko ìyà tí wọn wà ní 2023

Àkọlé fídíò, Kola Ologbondiyan: PDP ni yóò mú ọmọ Nàíjíríà kúrò lóko ìyà tí wọn wà ní 2023
Published

Akọwe ipolongo fun ẹgbẹ oselu PDP, Kola Ologbondiyan ni gbogbo nnkan ti ẹgbẹ oselu APC sọ pe awọn yoo se lasiko ti wọn n pologo ibo, lati bi ọdun mẹfa si asiko yii, ko si eyi ti wọn mu ṣẹ.

Ologbondiyan ni "ti a ba ni ki a gbe ẹgbẹ oṣelu APC si ori iwọn, òdo pọnbele ni wọn gba nitori ko si larija aseyọri kankan paapaa julọ lori ọrọ eto aabo.

O fikun pe oju ọmọ Naijiria ti la ju pe ki eniyan maa se nnkan to pinu lati ṣe i ko ba ṣe awọn ọmọ Naijiria yoo yọ danu.

O wa rọ awọn ọdọ ati obinrin lasiko yii lati wa dije nitori pe ẹgbẹ PDP ti fi aaye silẹ lati mu ki nnkan ki o rọrun fun wọn

Akọwe ipolongo fun ẹgbẹ oselu PDP,ní lasiko yii, owo ìkanlẹkun nikan ni PDP n gba bayii lojuna lati mu ki awọn eniyan le darapọ mọ ẹgbẹ, ki wọn si le kopa ninu eto oselu.