Philosophy of Ori: Olatunji ní orí ẹni ló ń dúró ti ní lọ́jọ́ ìṣòro àti lójú ikú

Àkọlé fídíò, Philosophy of Ori: Olatunji ní orí ẹni ló ń dúró ti ní lọ́jọ́ ìṣòro àti lójú ikú
Published

Awọn baba nla wa lo maa n pa a lowe pe ori ni a ba bọ, ka fi orisa silẹ nitori ko si orisa to n gbe ni bii ori ẹni.

Wọn a tun ni orisa lo ni ọjọ kan ipọnju, ori ẹni lo ni ọjọ gbogbo.

Sugbọn fun ọpọ ọmọ ilẹ Kaarọ Oojire, o loju ẹni to mọ itumọ ori bibọ, pataki rẹ ati ba se le bọ ori wa, ti yoo fi gbe wa.

Ọna lati mọ iwulo ori bibọ lo mu BBC Yoruba kan si Babalawo kan, Efuwape Olatunji, ẹni to salaye bi a se n bọ ori ati iwulo rẹ fun ẹda kọọkan.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Baba awo Afuwape ni ori ni ayanmọ ati Ẹlẹda ẹni, ko si yẹ ka wa laye lai bọ.

O ni ori lo n duro ti ẹda lojoojumọ, lasiko isẹlẹ ibi ati ni ọjọ iku ẹni pẹlu.

O wa fi ẹsẹ Ifa kan tọ ọrọ rẹ lẹyin eyi to sọ pataki ori bibọ, to si tun se afihan ọna to yẹ ka gba lati maa bọ ori wa loore koore.