June 12 protest: Ọlọ́pàá yin tíá gaàsì lu àwọn olùwọ́de l'Eko, wọ́n ní ìjà àráàlù
Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu, ti sọ pe ẹtọ awọn araalu labẹ ofin ni lati ṣe ifẹhonuhan lasiko to ba wu wọn.
O ni ẹtọ awọn gẹgẹ bii agbofinro ni lati fun awọn olufẹhonuhan ni abo to peye lasiko irufẹ iwọde bẹẹ.
Odumosu ṣalaye pe awọn kan to n sun taya laarin oju ọna to lọ si Maryland, ti wọn si kọ lati fi oju ọna ọhun silẹ ni awọn ọlọpaa yin gaasi taju-taju si lọjọ Satide.
- Wo ohun tó mú kí àyájọ́ June 12 ṣe pàtàkì fún Nàíjíríà
- Bobrisky fi òkò ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sáwọn tó ń ro ikú rò ó torí iṣẹ́ abẹ ìdí tó ṣe
- Kudirat Abiola: Akọni obìnrin tó jẹ́ ọ̀wọ̀n ìrántí fún àyájọ́ ìjọba alágbádá
- ₦324bn la pín fún 136,000 oníṣòwò ké kè ké lásìkò ìgbélé Covid-19 - Buhari
- Àwọn Ẹ̀gbá àti Òwu ń ṣàárò MKO Abiola, wọ́n ní ikú bọlá jẹ́
Gẹgẹ bi o ṣe sọ "Awọn ọmọ mi sọ fun awọ eeyan naa lati ṣi ọna ki awọn to n lọ ibi iṣẹ oojọ wọn le ri aye kọja, ṣugbọn wọn kọ jalẹ."
"Lẹyin ti wọn kọ ni mo ni ko buru, pe ki awọn ọmọ mi fun wọn ni taju-taju diẹ ki wọn le kuro loju lọna nitori ti a ba ni ki a lo ibọn, nnkan mii le ṣẹlẹ."
Ọga ọlọpaa naa sọ pe awọn gbe igbesẹ ọhun ki awọn to n jade lati inu Eko atawọn to n wọ Eko le ri ọna kọja.
Lẹyin naa lo gba awọn oluwọde naa nimọran pe ki wọn maa kọ iwe si ijọba ati ileeṣẹ ọlọpaa lọjọ miran ti wọn ba fẹ ṣe iwọde ki ileeṣẹ ọlọpaa le pese abo to peye fun wọn.
Bi iwọde naa ṣe n lọ niluu Ibadan naa lo n waye ni ipinlẹ Eko, Ondo, Osun, Rivers, ati Abuja.