Down Syndrome Skill centre: Wo bí ọmọ tí ọpọlọ wọn kù díẹ̀ ṣe ń kọ́ iṣẹ́ agẹrun, ọ̀sìn adìẹ̀, ẹja àti aṣọ fífọ̀

Published

Ẹda ko ni aropin, ko si dara ka maa ro eeyan pin nitori ko si ẹni to mọ ohun ti Ọlọrun yoo se.

Ọpọ ọmọ ti ọpọlọ rẹ ko pe to, ti wọn n pe ni aisan Down Syndrome lawọn obi wọn ti pa ti, pẹlu ero pe wọn ko le jẹ eeyan mọ nile aye.

Laipẹ yii si ni BBC Yoruba se fidio kan nibi ti baba kan, Usman Yahaya, to ni ọmọ alarun Down Syndrome yii, Dayo, ti safihan ọmọ rẹ to n kọsẹ ọwọ.

Igbesẹ yii lo wa yii ero ọpọ obi to niru awọn ọmọ bayii pada pe wọn si le se rere nile aye, ti ọpọ wọn si n tọ Baba Dayo lọ pe bawo lo ti see.

Eyi lo mu ki Yahaya da ibudo kan silẹ fawọn ọmọ to ni aisan Down Syndrome, nibi ti wọn ti n kọ isẹ ọwọ bii ọsin adiẹ ati ẹja, irun gigẹ ati asọ fifọ.

Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori idasilẹ ibudo yii, Yahaya salaye pe o rọrun fawọn ọmọ to ni Down Syndrome lati kọsẹ ọwọ, to si rọ awọn obi lati mase ta wọn nu.