Down Syndrome Skill centre: Wo bí ọmọ tí ọpọlọ wọn kù díẹ̀ ṣe ń kọ́ iṣẹ́ agẹrun, ọ̀sìn adìẹ̀, ẹja àti aṣọ fífọ̀
Ẹda ko ni aropin, ko si dara ka maa ro eeyan pin nitori ko si ẹni to mọ ohun ti Ọlọrun yoo se.
Ọpọ ọmọ ti ọpọlọ rẹ ko pe to, ti wọn n pe ni aisan Down Syndrome lawọn obi wọn ti pa ti, pẹlu ero pe wọn ko le jẹ eeyan mọ nile aye.
Laipẹ yii si ni BBC Yoruba se fidio kan nibi ti baba kan, Usman Yahaya, to ni ọmọ alarun Down Syndrome yii, Dayo, ti safihan ọmọ rẹ to n kọsẹ ọwọ.
- Ọmọ Downsydrome ti mo bí ló fún mí láǹfàní láti de ilú Oyinbo
- Báwo ni mo ṣe lè sọ̀rọ̀ ìtùnú fún ẹni tí ọ̀kan rẹ̀ dàrú?
- Wo ọ̀nà to le gbà tọ́jú arúgbó rẹ lásìkò tí ọpọlọ wọn bá kù díẹ̀ lọ́jọ́ ogbó
- Awọn ọmọ Yoruba ni Hollywood
- Aarun ọpọlọ kii se idajọ iku - Dokita
- 'Mo lè fi ẹsẹ̀ mi jẹun, fọṣọ, mó tún lè fi gbá ẹni tó bá ṣẹ̀ mí létí'
- Mo fẹ́ pa ara mi nígbà tí ariwo orin níbi ìnáwó kan sọ mí di adití - Kemi Dairo
- Dokita sisẹ abẹ fun alaisan ti ko yẹ
- Láì lo Kakulétọ̀, mo ní ọpọlọ ìṣirò, tábìlì ìṣirò wà lórí mi - Human Calculator
Igbesẹ yii lo wa yii ero ọpọ obi to niru awọn ọmọ bayii pada pe wọn si le se rere nile aye, ti ọpọ wọn si n tọ Baba Dayo lọ pe bawo lo ti see.
Eyi lo mu ki Yahaya da ibudo kan silẹ fawọn ọmọ to ni aisan Down Syndrome, nibi ti wọn ti n kọ isẹ ọwọ bii ọsin adiẹ ati ẹja, irun gigẹ ati asọ fifọ.
Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ìgbẹ̀yìn àwọn ọlọ̀tẹ̀ Yorùbá tó ran Fulani lọ́wọ́ láti kógun ja ìlú Osogbo
- Ìtàn ìgbé ayé Bode Thomas rèé, ó kọ́ wa láti máa kó ẹnu wa ní ìjánu
- Ṣo mọ̀ pé J.F Odunjo jẹ aṣòfin àti mínísítà nílẹ̀ yìí, yàtọ̀ sí pé ó jẹ́ òǹkọ̀wé?
- Ìtàn Àrọ̀gìdìgbà jẹ́ kí ń rò pé bàbá mi yan Yemọ̀ja ní àlè - Ọmọ Fagunwa
- Ó pé ọdún mẹ́rìnlélàádọ̀ta tí Akintola kú, ìdí abájọ ìja rẹ̀ pẹ̀lú Awolowo rè é
- Ìtàn Gbọnka àti Timi, akọni méjì tó borí Aláàfin Ṣango
- Wo ìṣẹ̀lẹ̀ márùn-ún tí kò bá pín Nàíjíríà sí yẹ́lẹ-yẹ̀lẹ
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori idasilẹ ibudo yii, Yahaya salaye pe o rọrun fawọn ọmọ to ni Down Syndrome lati kọsẹ ọwọ, to si rọ awọn obi lati mase ta wọn nu.

