Lagos Tanker Explosion:Ọkọ̀ agbépo míràn tún gbiná l‘Eko
Published
Ọkọ agbepo kan ti gbina ni agbegbe Oshodi ni ilu Eko.
Aworan ati fọnran fidio iṣẹlẹ naa to wa loju opo Twitter ṣafihan pe ina nla n jo nitori ọkọ agbepo naa to dẹgbẹ lulẹ.
Iṣẹlẹ yi si ti mu ki sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ wa ni ọna mejeeji to wọ Oshodi iyẹn ibudokọ Toyota ati oju ọna marose Apapa.
Titi di igba ta fi n ko iroyin yi jọ awọn oṣiṣẹ panapana ati ajọ iṣẹlẹ pajawiri n gbiyanju lati pa ina naa.
Atẹjade lati ọdọ ọga agba LASEMA Dokita Damilola Oke-Osanyintolu ni oṣiṣ awọn ati oṣiṣẹ panapana ti dkun ina naa.
O ni awọn ṣi n ṣiṣẹ lati ri pe wọn gbe ajoku ọkọ agbepo naa kuro ni oju ọna.
Ko ti si ikede kankan pe ẹnikẹni ba iṣẹlẹ ina yi lọ.