Ọba Samule Kolapo Adegbite Adedoyin: Wo ohun tí wọ́n sọ nípa Owa Ale ìlú Ikare tó wàjà

Àkọlé fídíò, Wo ohun tí wọ́n sọ nípa Owa Ale ìlú Ikare, Ọba Samule Kolapo Adegbite Adedoyin tó wàjà
Published

Ọjọ kinni, oṣu Kẹsan an, ọdun 2020 ni Owa Ale ti ilu Ikare, Ọba Samule Kolapo Adegbite Adedoyin jade laye lẹyin to ti lo ọdun mejidinlaadọta lori itẹ.

Ọpọ awọn ara ilu Ikare atawọn ẹbi Ọba alaye naa lo n ṣedare lẹyin rẹ lẹyin to lọ darapọ mọ awọn baba nla rẹ lẹni ọdun marundinlaadọrun un.

Nigba ti ikọ ileeṣẹ iroyin BBC ṣe abẹwo si aafin rẹ lọjọ to papoda, aṣoju rẹ, Oloye Olabisi Babajide sọ iru eeyan ti Ọba alaye naa jẹ ko to waja.

O ni “Owa Ale jẹ ẹni to ko awọn eeyan mọra, o si tun jẹ ẹni to ni iwa tutu.”

Bakan naa ni Oloye naa tẹsiwaju pe akoko Ọba alaye ọhun san awọn eeyan ilu Ikare nitori pe oriṣirṣi awọn ilọsiwaju lo de ba ilu naa lasiko to wa lori oye.

Oloye babajide tun mẹnuba diẹ lara oriki Kabiesi naa.

Ẹ wo fidio yii fun ẹkunrẹrẹ.