Goitre Patients: Àwọn èèyàn tó ní àrùn gẹ̀gẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìkórira àti ìdẹ́yẹsí ní àwọn ń kojú

Published

“Ọpọ wa lo ti n gbe arun gẹgẹ yii kiri fun ọdun mẹwa, mẹẹdogun ati mẹẹdọgbọn nitori ẹru n ba wa lati se isẹ abẹ.”

Eyi ni ibẹru ti ọkan lara awọn eeyan to ni arun gẹgẹ nilu Badagry fihan fun ikọ iroyin BBC Yoruba lasiko to n ba wa sọrọ.

Awọn alarun gẹgẹ naa ni ẹrun isẹ abẹ n ba awọn lati se nitori awọn le e ku, lo mu kawọn pinnu lati mase se isẹ abẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Koda, wọn fidi rẹ mulẹ pe agbo ni awọn n lo si arun naa, amọ fun ọpọ ọdun, bakan naa ni ọmọ se ori.

Ọpọ wọn si lo sọ nipa idojuti, idẹyẹsi ati ikorira ti wọn n koju lawujọ nitori arun gẹgẹ to n ba wọn finra.

Sugbọn pupọ wọn ti setan bayii lati lọ fun isẹ abẹ lẹyin ti wọn ri awọn eeyan to se isẹ abẹ arun gẹgẹ nipinlẹ Eko, ti iku ko si pa wọn.