Oladapo Adu: Nàíjíríà já mi kulẹ̀ torí wọn kò wá gbé mi

Àkọlé fídíò, Oladapo Adu: Nàíjíríà já mi kulẹ̀ torí wọn kò wá gbé mi
Published

Yoruba ni bi eegun ẹni ba joo re, ori a maa ya atọkun amọ eyi ko ri bẹẹ fun Oladapo Adu, to lọ soju Naijiria ninu idije Chess ni Sierra-Leone.

Adu, ẹni to jẹ ọmọ Naijiria to n gbe ni orilẹede Amẹrika salaye pe Naijiria lo mu awọn mẹrin lati soju rẹ ninu idije Chess lai gbe owo kalẹ fi se agbatẹru wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni funra oun ni oun ra tikẹẹti alọ ati abọ lati lọ si Sierra Leone, amọ nigba ti idije naa pari logunjọ osu kẹta, arun Coronavirus ti bẹ silẹ.

Coronavirus yii si lo mu ki ọkọ ofurufu oun wọgile eto irinna rẹ, ọkada si ni oun gun lati Freetown lọ si Abidjan ni ọjọ kẹrinlelogun osu kẹta ọdun yii.

Adu ni awọn orilẹede yoku ni iwọ oorun Afirika wa ọna lati gbe awọn asoju wọn nibi idije naa amọ Naijria ko tiẹ ranti oun, tawọn mẹta yoku ti wọn jọ soju Naijiria si ti pada sile.