Lagos lockdown update: Ayodeji Tinubu ní àìsí àǹfàní ẹ̀kọ́ ayélujára t'íjọba ń pariwo fáwọn ọmọdé agbègbè òun lòun fi di olùkọ́ fún wọn

Àkọlé fídíò, Lagos lockdown update: Ayodeji Tinubu ní àìsí àǹfàní ẹ̀kọ́ ayélujára t'íjọba ń pariwo
Published

Lasiko igbele to waye nipasẹ ajakalẹ arun coronavirus, oniruuru eto lo yipada lawujọ ninu eyi ti eto ẹkọ wa.

Gẹgẹ bi ara ọna lati mojuto awọn iyipada yii lo mu ki ijọba ni ipinlẹ Eko o gbe eto ẹkọ ayelujara ati ti ori afẹfẹ jade.

Amọṣa, bi eto naa ṣe loriyin to, ọpọ akẹkọ ni ko lọtọ si nitori aisi anfani ayelujara ati idakureku ina ọba.

Eyi lo mu ki Ọgbẹni Tinubu Ayọdeji, ninu itara rẹ lati rii pe awọn ewe agbegbe rẹ ko padanu nitori airi anfani ayelujara naa lo fi da eto ẹkọ jẹle o sinmi silẹ eleyi ti awọn eeyan ti n kan sara si bayii.