Michael Jordan: $560,000 ni wọn lu gbàǹjo bàtà ìlúmọ̀ọ́ká agbábọ́ọ́lùù àlápẹ̀rẹ̀ náà fún ẹ̀ṣọ́ ilé

Michael Jordan

Oríṣun àwòrán, Sotheby's

Published

Bata ti ilumọọka agbabọọlu alapẹrẹ, Michael Jordan lo ni ọdun 1985, ni wọn ti lu gbanjo rẹ ni ẹgbẹrun lọna ọtalelẹẹdẹgbẹta dọla ($560,000).

Bata olokun buutu naa, ti Ileesẹ Nike ṣe sita, eyi ti Jordan wọ lasiko saa bọọlu alapẹrẹ to fi dojukọ ikọ Chicago Bulls, nireti wa tẹlẹ pe owo tita rẹ yoo wa laarin ẹgbẹrun lọna ọgọrun si ẹgbẹrun lọna aadọjọ dọla nilu Sotheby.

Akọsilẹ to wa nilẹ salaye pe, ojilenirinwo o din meji ati aabọ dọla ($437,500) ni wọn ta ẹsẹ bata Nike yii lọdun 1972.

Awọn ẹsẹ bata buutu ti ko bara dọgba ni Jordan n wọ, ẹsẹ osi rẹ n wọ iwọn bata mẹtala nigba ti ẹsẹ ọtun rẹ n wọ iwọn ẹsẹ bata mẹtala ati aabọ.

Jordan Geller, to da ibudo iṣe nkan iṣẹnbaye lọjọ si silẹ nilu Las Vegas, lo ta bata ti Michael Jordan lo pati lọdun 1985 naa.

Michael Jordan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Igbesẹ tita bata naa si lo bọ si akoko ti Ileesẹ Netflix gbe akanse ẹkunrẹrẹ fọnran aworan iroyin kan sita, to pe akori rẹ ni - The Last Dance.

Afihan ifiga-gbaga fun idije ami ẹyẹ agbabọọlu alapẹrẹ to fakọyọ julọ, ikẹfa iru rẹ to waye laarin saa idije bọọlu alapẹrẹ fọdun 1997 si 1998 si wa ninu fọnran akojọ aworan fun akanse eto naa.