Coronavirus Lockdown: Bí Coronavirus ò pani, ebi yóò pani bí a kò bá tajà, àwọn ọlọ́jà ní Bódìjà ṣàlàyé

Àkọlé fídíò, Coronavirus Lockdown: Bí Coronavirus ò pani, ebi yóò pani bí a kò bá tajà, àwọn ọlọ́jà ní
Published

Ọpọ eeyan lo ti kọminu lori akoba ti awọn igbesẹ ti ijọba lẹkajẹka gbogbo n gbe lati dena itankalẹ arun coronavirus ni lorilẹede Naijiria.

Lootọ arun yii kii ṣe eyi ti o gọdọ tan kalenkako, sibẹ awọn araalu n lọgun pe aisi abuja lọrun ọpẹ lori ọna ti mu ounjẹ wọ inu ẹbi kọọkan ti mu ki ọrọ naa di eyi to so si ni lẹnu bu iyọ sii.

Ni ilu ibadan, paapaajulọ ọja Bodija nilu Ibadan, kẹtikẹti lawọn eeyan n tu wa sita lati na ọja wọn lai naani ọrọ ijinasiraẹni ti oloyinbo n pe ni self distancing.

Eyi lo sun akọroyin BBC News Yoruba, Adedayọ Okedare lọ ṣe ẹ nlẹ n bẹun si wọn lati mọ ki lo n ṣẹlẹ gan an.

Afikun nipa aarun Coronavirus
Banner