Contortion: Nígbà tí mo rí bí ara Soffie Dossi ṣe rọ̀, mo pinu pé mo lè ṣe bẹ́ẹ̀

Àkọlé fídíò, Láì rọ lápa rọ lẹ́sẹ̀, ẹ wo ọmọ ọdún mọ́kànlá tó ń lọ́ ara lóríṣi ọ̀nà
Published

Ọmọde ni ara rẹ rọ to yii.

Ọmọ ọdun mọkanla ni Fopefoluwa Ayo-Oyalowo to tete mọ iru ẹbun ti Ọlọrun fun un to si n mu u lo lati majesin.

Latigba to ti wa ni ọmọ ọdun marun lo ti mọ pe oun ni ẹbun naa.

"Bí mo bá ti jí, tí mo pàrọ̀ aṣọ, máà gbé orin sí i, iṣẹ́ lílọ ara bẹ̀rẹ̀ nìyẹn".

Fopefoluwa ni nigba ti oun lọ wo ori ayelujara fun fọnran awọn to ti di gbajugbaja ninu iru ohun to yan laayo yii, o pinu lọkan ara rẹ pe oun le ṣe ohun ti wọn n ṣe daadaa. O ni "Soffie Dossie, gbajugbaja to n lọ ara ni awokọṣe mi".

Lori awọn obi to maa n pa ina ẹbun amutọrunwa mọ awọn ọmọ wọn lara, Fopefoluwa sọ ọrọ iṣiti fun wọ.