Supreme court judgement: Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ PDP fẹ̀hónúhàn nílé ẹjọ́ gíga jùlọ

Àkọlé fídíò, Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ PDP fẹ̀hónúhàn nílé ẹjọ́ gíga jùlọ
Published

Ọgọọrọ awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu PDP lo ṣewọde niluu Abuja lọjọ Aje lẹyin idajọ ileẹjọ giga julọ to f'ountẹ lu Gomina Abdulahi Ganduje gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori nipinlẹ Kano.

Awọn adajọ ẹlẹni meje ti Adajọ agba Naijiria, Muhammed Tanko ṣaaju da ẹjọ ti Abba Yusuf to jẹ oludije lẹgbẹ oṣelu PDP pe lati tako wiwọle Gomina Ganduje ti ẹgbẹ oṣelu APC nu.

Eyi lo mu kawọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu PDP bẹrẹ ifẹhonuhan ninu eyi ti wọn ti n sọ pe awọn ko faramọ idajọ ileẹjọ to giga julọ.