VAT: Kò sí àǹfàní kankan tí ìjọba ti ṣe fún mi sẹ́yìn
O yẹ ki ijọba ṣaanu awọn eniyan lasiko yii ni ero awọn kan.
Ni kete ti iroyin ti jade pe ijọba Naijiria fẹ bẹrẹ igbesẹ gbigba owo ori lori ọja ti a ba ra lori ayelujara ni BBC Yoruba ti jade.Láti January lọ, gbogbo ẹni tó bá ra ọjà lórí ayélujára yóò máa sanwó orí - FIRS
BBC lọ beere ero awọn ọmọ Naijiria ti ọrọ naa kan julọ lori koko yii.
Owo ori sisan ko ṣe ajeji sawọn eniyan Naijiria ṣugbọn wọn kii san an lori ọja ayelujara tẹlẹ.
Ọpọlọpọ ninu awọn ti a gbọ ọrọ wọn ni wọn ni wọn ko mọ anfani kan pato ti ijọba Naijiria n ṣe fun wọn to mu sisan owo ori tuntun yii dani.
Awọn miran gba pe igbesẹ to dara ni ki a bẹrẹ sini san owo ori lori ọja ti a ra lori ayelujara.
Wọn ni o wa fun idagbasoke Naijiria ni ti ijọba ba lo owo ti wọn ba pa daadaa.
Loju awọn miran igbesẹ yii ko ni rọrun fun awọn mẹkunnu rara ni Naijiria.