Kílò fa èdè àìyedè láàrin ìjọba àti àwọn ọmọ lẹ́yìn El-Zakzaky?

Àkọlé fídíò, Kílò fa èdè àìyedè láàrin ìjọba àti àwọn ọmọ lẹ́yìn El-Zakzaky?
Published

Ìdásílẹ̀ Shi'ite bẹ̀rẹ̀ ní ọgbọ̀n ọdun lé díẹ̀ sẹ́yìn ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ orílẹ̀-èdè Iran àti Iraq níbi ti wọ́n pọ̀ si jùlọ.

Àwọ́n ọmọ ẹgbẹ́ Shi'ite kò jú mílíọnù mẹ́rin lọ ti àwọn musulumi Sunni si fẹ́ẹ̀ tó ọgọ́run kan mílíọnu ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ìyàtọ ìlànà ìgbàgbọ́ Sunni àti Shi'ite lo kun ǹkan to fa èdè àìyede to n bẹ́ sílẹ̀, tó fi mọ ìbérèrè bí tani adele Muhammed lẹ́yì to ti ku

Ìwádìí fi hàn pé ni ọdún 2016 ilé ẹjọ fidi rẹ̀ múlẹ̀ pé, ọ̀ọ́dúrún ọmọlẹ́yìn El-Zakzaky ni àwọn ọmọogun orilẹ̀-èdè Nàìjíríà pa.

El- Zakzaky ṣe agbékalẹ̀ ofin, ilé ẹkọ, ilé ìwòsàn ni ìlanà ìgbàgbọ́ Shíà ní àwọn ìpínlẹ̀ Ariwa Nàìjíríà, tí orílẹ̀-èdè Iran àti Iraq sí ń ṣe agbátẹru wọ́n.

Ìjọba orilẹ̀-èdè Nàìjíríà dojúkọ wọ́n nígbà ti wọ́n ni ìlànà òfin tí àwọn ni awọn yóò maa lò láì bọ̀wọ̀ fún òfin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, èyí ti ijọba si lòdì sí gede ń gbe