AFCON 2019: Debola olólùfẹ́ Super Eagles mú BBC Yorùbá dé ibùdó Bọ́ọ̀lù wíwò

Àkọlé fídíò, Ẹ wo bí àwọn olólùfẹ́ Super Eagles ṣe tú lọ sí ibùdo
Published

Ere Bọọlu jẹ ere idaraya kan ti awọn ọmọ Naijiria kii fi ṣere rara yala labẹle tabi lẹyin odi.

Bi idije ife ẹyẹ AFCON ṣe ti n lọ lọwọ ni Alexandria orilẹede Egypt, awọn ọmọ Naijiria ni awọn ọmọ Naijiria ṣe n tu jade lọ si ibudo iworan bọọlu.

Ọpọ ma n ri i pe eleyii ma n dun ju ki eeyan kan dede jokoo sinu ile lati da wo ifẹsẹwọnsẹ naa ayafi ti awọn ololufẹ bọọlu bii tiwọn ba wa nibẹ.

BBc Yoruba jade lati dara pọ mọ awọn ololufẹ ikọ Super Eagles lati jọ wo ifẹsẹwọnsẹ AFCON 2019 to n waye lọwọ lọwọ.