World Smallest Baby: Dípò oṣù mẹ́sàn-án, wọ́n bí ọmọ yìí ní oṣù mẹ́rin àbọ̀
Published
Saybie ni inagijẹ ti wọn fun un.
Pẹlu akọsilẹ, igbagbọ ni wi pe Saybie ni ọmọ ti wọn bi ti iwọn rẹ kere ju lọ to si ye e.
Gbogbo ìwọ̀n rẹ̀ kò ju èso Apple lọ lọjọ ti wọn bi i.
Ni ọsẹ mẹtalelogun iyẹn nkan bii oṣu mẹrin abọ, dipo oṣu mẹsan ti iya fi n gbe ọmọ ni wọn fi iṣẹ abẹ pajawiri gbe e jade ninu iya rẹ.
Wọn dá a dúró sile iwosan lati maa woye boya yoo ye e.