Iná Ibadan: Gbogbo dúkìá tó wà lókè ilé alájà kan náà ló jóná tán
Published
Lasiko ti wọn n ba BBC Yoruba sọrọ, awọn olugbe inu ile naa rawọ ẹbẹ si awọn ẹlẹyinju aanu ọmọ ilẹ yii lati se iranwọ fun wọn, lori awọn dukia wọn to jona mọle.
Wọn salaye pe, awọn gbiyanju lati sare ko awọn ohun elo to n bẹ ninu ile naa jade lasiko ti eefin bẹrẹ sini ru.
Sugbọn wọn ni pupọ ninu awọn ohun elo naa ni ina ọmọ ọrara ti sọ di eeru, ki awọn aladugbo to gbe omi ati awọn ohun elo mii ti wọn fẹ fi pa ina to de.