Ọbasanjọ: N kò ní dẹ́kun láti máa tako Buhari

Buhari ati Ọbasanjọ nki ara wọn
Àkọlé àwòrán, Ọbasanjọ ti kọ lẹta si Buhari eleyi to di gbajugbaja kaakiri agbaye
Published

Aarẹ tẹlẹri lorilẹede Naijiria, Olusegun Obasanjo ti ni, idi ti oun fi n tako Aarẹ Buhari ni wi pe isejọba tiwantiwa fayegba ki eniyan o sọrọ nipa ijọba to wa lode.

Aarẹ Obasanjo ni asiko to n se ayẹyẹ ọdun kejilelogun ni ilu abeokuta sọ wi pe ko si ija laaarin oun ati Aarẹ Muhammadu Buhari.

O ni isẹ ilu kii se ohun ti eniyan fi n se ibatan, amọ o nii se pẹlu titako igbesẹ ijọba ti ko ba ba awọn eniyan lara mu.

Ni ọpọ igba, Aarẹ tẹlẹri lorilẹede Naijiria, Olusegun Obasanjo ti ma n bu ẹnu atẹ lu isejọba Aarẹ Muhammadu Buhari.

Àkọlé fídíò, Olusegun Obasanjo: Ọmú ìyá mi ti mo fi ń mùkọ ni kekere ló jẹ ki ń lókun